Ewo tun lawon oba Yoruba se fun wa yii

Spread the love

Inu mi ko dun rara. Ibanujẹ gidi ni. Loootọ mo ti dagba kọja ẹni ti i ja mi loju bi iru awọn nnkan bayii ba ṣẹlẹ, ṣugbọn ibanujẹ to mu mi ju ki n sunkun lọ. Lati bii ijẹta ni kinni naa ti wa lara mi, ko ti i kuro titi di bi mo ṣe n sọ yii. Koda, n ko le ranti ọjọ tinu mi bajẹ bayii ri.

Boya ẹyin naa ti gbọ, tabi ẹ ti ri i. Fidio awọn ọba Yoruba kan wa lori ẹrọ ayelujara kari aye bayii, nibi tawọn ọmọ ẹyin Bọla ti n fi apoowe ha owo fun wọn. O gbebẹ, awọn ọba nla ni wọn. Awọn ọba to yẹ ki wọn sọrọ ki gbogbo ilẹ Yoruba gbọn pẹpẹ, awọn ọba to yẹ ki wọn ṣaaju, ki Yoruba tẹle wọn. Awọn ni gbogbo aye ri gẹgẹ bii onijẹkujẹ yii o, ti gbogbo aye n wo gẹgẹ bii ọba to n gba ẹgunjẹ kiri, ti wọn si sọ ara awọn doniyẹyẹ ati alaimẹtọ loju awọn ẹya to ku ni Naijiria, paapaa awọn Hausa ati Ibo. Eleyii ma buru o! Haa, asiko yii o daa fun Yoruba rara.

Igba ti mo ti ri iroyin naa lakọọkọ laya mi ti ja. Iroyin gbe e pe awọn ọba Yoruba lọọ ki Bọla nile ẹ l’Abuja, nigba ti n o si tun ri wọn fẹrẹ, wọn ni wọn lọ sọdọ Buhari. Iru ọrọ bẹẹ ye mi daadaa, mo mọ ohun to ṣẹlẹ. Idi taya mi fi ja niyẹn. Akọkọ ni pe nigbakigba ti ẹ ba ti ri awọn ọba adugbo kan ti wọn to tẹle ara wọn lẹyin bayii, ki i ṣe Aarẹ lo ranṣẹ pe wọn o, bẹẹ ni ki i ṣe awọn ni wọn fẹẹ ri Aarẹ, awọn oloṣelu kan lo pe wọn, wọn yoo kan dẹ pakute oro naa fun wọn ni. Ẹnikan ni yoo pe wọn, o le jẹ gomina ipinlẹ wọn, yoo ni ki wọn waa lọọ ki Aarẹ, ko le mọ pe tiẹ lawọn ọba awọn n ṣe. Awọn ni wọn aa sanwo ẹronpileeni, wọn yoo sanwo otẹẹli, wọn yoo si ṣeto owo nla ti wọn yoo fun ẹnikọọkan wọn. Awọn ọba Yoruba ti wọn lọ si Abuja yii, awọn Bọla lo ṣeto ẹ, wọn kan fẹẹ fi wọn gbarawọ lasan loju Buhari ni.

Asiko ti a wa yii, pẹlu awọn ipo irọ ati ẹtan tawọn Buhari ni awọn n gbe fun Bọla, gbogbo ọna pata lo n wa lati fi sọ fun Buhari pe gbogbo ọmọ Yoruba lo wa lẹyin oun, eyi naa lo si ṣe to fi fawọn ọba wa ṣe yẹyẹ yii o. Awọn oniroyin gbe e lọsẹ to kọja pe ara Bọla ko ya, o wa lọsibitu ni Abuja, awọn to ri i lọhun-un sọ, ṣugbọn wọn pana ọrọ naa mọlẹ, wọn ni irọ ni, ara arẹ ya. Nigba to di ọjọ kẹta lẹyin iyẹn, awọn ọba Yoruba to tẹle ara wọn: Ọọni ṣaaju, Alake tẹle e, Ayangbunrẹn Ikorodu wa lẹyin ẹ, Deji Akurẹ, Asẹyin, Olukarẹ atawọn mi-in, wọn lawọn n lọọ ki Bọla ni Abuja. Ṣe Abuja ni ile Bọla ni, tabi o n fọmọ fọkọ nibẹ, tabi o n ṣe oku ana! Nigba wo lo di ohun ti odidi Ọọni, olori gbogbo Yoruba pata, yoo gbera, ti yoo ni oun n lọọ ki oloṣelu kan lẹyin odi. Bi awọn ọba yii ko ba le pe Bọla wa si Ifẹ tabi adugbo wọn, kin ni wọn ko duro ko pada si Eko ki wọn lọọ ri i si.

Awọn funra wọn kọ lo wa nidii ọrọ yii o. Ọkan ninu awọn oloṣelu, tabi gomina kan ni yoo ti ni ki wọn waa lọ ki Bọla o, kawọn Hausa ti wọn fi i sipo le mọ pe o lero lẹyin o. Bẹẹ awọn oloṣelu yii mọ, Ọọni atawọn ọba to ku yii mọ, gbogbo ẹni to ba woye ọrọ yii yoo mọ, pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii, awọn eeyan yii n tan Bọla ni. Loootọ oun naa n tan wọn, ṣugbọn ete tiwọn ju tiẹ lọ, ibi ti wọn si ti mu un ko daa. Ki i ṣe nitori wọn fẹran ẹ ni wọn ṣe fi i sipo, ti Buhari ni ko maa boun ṣe kampeeni kiri, wọn kan fẹẹ fiyẹn de e lọwọ sẹyin ki wọn ri i pe ko sibi to le lọ ni. Wọn yoo ti ṣeto awọn owo buruku kan sọwọ e bayii ti wọn yoo fi mu un lẹyin ọla bo ba ni oun jẹun, oun yo tan, oun wa n wa bẹkunbẹkun kaakiri. Ṣebi bi wọn ṣe ṣe fun un ni 2015 niyẹn. Awọn ọba wa gbọdọ mọ eyi, kin ni wọn tun da tiwọn si i si. O di ọba ilẹ Hausa meloo to ko ara wọn lẹyin, ti wọn ni awọn n wa oloṣelu ilẹ Hausa lọ. Ọba Kano ni abi ọba Sokoto!

Bawọn ọba yii o ba le ba Bọla sọ ootọ ọrọ, ṣebi wọn aa maa woran oun atawọn ti wọn jọ n tayo, ẹni to ba le pa ẹnikan layo ninu wọn. Mo sọ fun yin pe awọn oloṣelu bii Bọla ko lojuti, wọn le ta odidi iran wọn nitori agbara oṣelu yii. Mo ṣalaye nigba kan ohun to ṣẹlẹ ni 2015, lẹyin tawọn Buhari wọle tan, ti wọn ko ranti awọn Bọla mọ, mo sọ fun yin pe Bọla ati Bisi (Akande), pe awọn ọmọ Yoruba Amẹrika pe ki wọn ba awọn kọwe si Buhari lati sọ pe inu awọn ọmọ Yoruba ko dun, awọn si n binu si oun Bọla to ni ki awọn tẹle Buhari. Awọn aṣaaju ọmọ Yoruba yii kọwe yii fun wọn, wọn si fi i ranṣẹ si Buhari. Bọla lo wọn lasan ni, nigba to ri ohun to n wa, ko ya sọdọ tiwọn mọ, o ti gbagbe wọn. Mo sọ fun yin pe ọba ti ẹ ba ti ri to n da sọrọ oṣelu, ọba bẹẹ yoo farapa gbẹyin ni.

O daju pe awọn ọba yii ko ro igbẹyin ohun ti awọn ṣe, nitori ọjọ n bọ ti Yoruba yoo beere ẹni to ran wọn niṣẹ ti wọn jẹ. Ohun ti wọn lọọ ki Buhari fun ko ye ẹnikẹni. Ṣe pe o ṣejọba daadaa ni, tabi pe o ṣe Yoruba loore. Ṣe Ọọni ni yoo sọ ohun ti Buhari ṣe si Ileefẹ ni, tabi Alake ni yoo sọ ohun ti Buhari ṣe si Abẹokuta, tabi awọn ọba yii yoo sọ pe awọn ko mọ gbogbo wahala to wa niluu yii ni. Kin ni wọn waa jẹ ki Bọla maa da wọn riboribo si. Ṣebi wọn pe Awujalẹ, ṣebi wọn pe Alaafin. Awọn ti gbọn, wọn ti mọ pe Bọla fẹẹ fawọn pawo lọdọ awọn Buhari ni, pe Buhari yoo ri i pe gbogbo ọba Yoruba lo wa lapo oun. Bẹẹ irọ ati ẹtan ni.

Ẹ waa wo eyi to buru ninu ọrọ naa ati abuku ti irin-ajo Abuja yii mu lọwọ. Ki i ṣe nnkan tuntun, bi awọn ọba ba rin iru irin-ajo bayii, ẹni ti wọn ba lọọ ba lalejo yoo fun wọn lowo, Aarẹ yoo fun wọn, awọn ọmọọṣẹ rẹ yoo fun wọn, koda, awọn ọmọ ilu wọn to ba wa ni Abuja yoo fowo ranṣẹ si wọn. Ki i ṣe tuntun. Ṣugbọn ibi ti wọn ba jokoo si ni kọrọ ni wọn ti n fi iru owo bẹẹ ta wọn lọrẹ. Eyi ti Bọla ṣe fun wọn ti ko daa ni lati jẹ kawọn onitẹlifiṣan wa nibẹ nigba to n ha owo fun wọn, to waa dohun ti kinni naa yọ lori ẹrọ ayelujara pe awọn ọba Yoruba lọọ gba owo l’Abuja. Bi ẹ ba bi aburo wa yii, yoo sọ pe oun ko mọ pe awọn onitẹlifiṣan wa nibẹ, oun ko sọ pe ki wọn ha owo fun wọn loju tẹlifiṣan, ṣugbọn o ti fi kinni naa ba wọn lorukọ jẹ titi aye wọn, yoo si ṣoro gan-an kawọn ọba yi too niyi loju awọn eeyan wọn bii ti tẹlẹ. Ki lawọn oloṣelu yii n ba aye Yoruba jẹ bayii si.

Ṣẹ ẹ mọ pe ọrọ ti mo si n sọ lọ lọsẹ to kọja niyẹn, ti mo ni iṣoro ni lati fi ọba kan ṣe aṣaaju wa, nitori awọn oloṣelu ni wọn n dari awọn ọba yii, ibi ti wọn ba dari wọn si ni, afi awọn ọba kọọkan to ba le duro jẹẹ, ti wọn ko wa iwakuwaa kiri, ti wọn si le sọ fawọn oloṣelu pe ipo ti awọn wa ju tiwọn lọ. Bọla ati Raufu ni wọn mọ bi Ọọni to wa lori oye yii ṣe debẹ, yoo si ṣoro ko too kọ ọrọ si wọn lẹnu. Ọọni ni yoo ja ara rẹ gba lọwọ wọn, ti yoo jẹ ki wọn mọ pe oun ni Ooni, ipo oun si ti sọ oun di baba fun gbogbo Yoruba pata.

Eyi tawọn Bọla n ṣe fun Yoruba yii ko daa, eyi tawọn ọba yii jẹ ki wọn lo awọn fun ibajẹ bayii ko sunwọn! Nijọ wo ni Yoruba yoo bọ ninu ẹgbin atabuku ti wọn fi rẹ gbogbo wa lara loju aye yii. Ta ni yoo pa ibi tawọn ọba Yoruba ti n gbowo rẹ lori ẹrọ ayelujara. Ọlọrun o, ti gbogbo ọmọ Yoruba ma dọwọ ẹ o.

 

 

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.