Ewo ni Tinubu n sọ lẹnu yii

Spread the love

Aṣiwaju Bọla Tinubu n ṣẹ awọn eeyan, o n ṣẹ awọn ti wọn fẹran rẹ, bi ko ba si jawọ, awọn ti wọn fẹran oun naa yoo ṣẹ ẹ, nitori wọn yoo sọrọ si i daadaa. Gbogbo ohun to ba ti ṣẹlẹ pata ni oun ati awọn eeyan rẹ maa n ti ọwọ oṣelu bọ, bi wọn yoo ṣe fi ẹtan mu araalu nikan lo jọ pe awọn fẹ. Ni ti Abiọla ti wọn fi oye da lọla, ko si ọrọ mi-in ti Tinubu ri sọ ninu gbogbo ohun to ṣẹlẹ nibẹ ju pe, “Pẹlu eyi to ṣẹlẹ yii, pẹlu eyi ti Buhari ṣe yii, gbogbo Yoruba ni yoo dibo fun un!” Haa, Aṣaaju! E e ṣe! Aṣaaju awọn oloṣelu “jẹun-soke ko o tun jẹun-sapo” yii mọ pe ọrọ ti oun sọ yii ko ri bẹẹ, o mọ pe ọpọlọpọ ọmọ Yoruba gbọn, wọn si mọ pe ki i ṣe ifẹ wọn ni Buhari ni to fi fi oye da Abiọla lọla, bo tilẹ jẹ pe gbogbo wọn lo fẹran ohun ti wọn ṣe. Ki lo de ti Aṣiwaju Tinubu ko le ba Buhari sọ ootọ ọrọ bi Wọle Ṣoyinka ti ṣe. Awọn nnkan wa nilẹ tẹlẹ ko too di pe ọrọ ti Abiọla yii de, bi Buhari ko ba si yanju rẹ, ọrọ ibo didi rẹ nilẹ yii yoo le diẹ. Lọjọ wo ni Buhari yoo ṣeto ti awọn Fulani ko ni i pa awọn eeyan mọ nilẹ yii! Lọjọ wo ni yoo ṣeto ti iwa ẹlẹyamẹya yoo dopin ninu ijọba rẹ! Lọjọ wo ni yoo yee fi ipo to dara julọ ta awọn Hausa-Fulani nikan lọrẹ. Bi Aṣiwaju Tinubu ba fẹran Buhari, to si fẹ ki Yoruba dibo fun un, awọn ohun ti yoo sọ fun un ree. Tabi Aṣiwaju yii ko gbọ nigba ti Buhari n sọ pe ko si iru Abacha laye mọ ninu awọn eeyan oniwa-daadaa! Tabi ki i ṣe awọn ṣọja Abacha ni Tinubu ni o le oun kuro niluu ni 1994 ni! Bi Buhari ba si ti sọ pe Abacha lo dara ju lọ laye, Tinubu ti gba naa niyẹn. Oṣelu ẹtan ni, nitori ki i ṣe awọn ohun to wa ninu Tinubu funra rẹ lo n sọ jade. Bẹẹ, opurọ ki i niyi, ẹtẹ naa ni yoo kangun rẹ. Nitori pe Aṣiwaju Tinubu n ba Buhari rin, ṣugbọn ko le ba a sọ ootọ ọrọ, iyẹn naa ni gbogbo iya to n jẹ wa yii ṣe n jẹ wa, iyẹn naa lo si sọ Yoruba di ẹni ti ko ja mọ kinni kan loju wọn. Bi Aṣiwaju awọn oloṣelu yii ba fẹran Buhari loootọ, yoo sọ ohun to yẹ ko ṣe fun un. Bo ba si jẹ loootọ lo fẹran Yoruba, ti ki i ṣe lati kan fi orukọ Yoruba ṣe oṣelu lasan, yoo mọ iru ọrọ ti oun yoo maa sọ nipo to wa. Ko dara lati fi oṣelu ba orukọ rere ẹni ati iyi ẹni jẹ, nitori ohun ti i tan leegun ọdun, ọmọ alagbaa yoo ra akara fi jẹkọ. Aye Buhari la wa loni-in, nigba ti awọn mi-in ba de lọla nkọ, nibo ni Aṣiwaju Tinubu yoo gbe oju si! Ka ma fi oni ba ọla ẹni jẹ o, nitori ọjọ n bọ ti a oo tun foju kan ara wa.

(126)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.