Eremọde ni igbimọ apaṣẹ APC ti Oshiomhole loun tuka nipinlẹ Ogun

Spread the love

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja yii ni Alaga apapọ egbẹ APC, Adams Oshiomohole, atawọn igbimọ amuṣẹṣe (NWC), tu igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ naa ka nipinlẹ Ogun ati Imo, wọn lawọn yoo yan awọn alaabojuto tuntun ti yoo maa mojuto bi nnkan ṣe n lọ lawọn ipinlẹ mejeeji yii.

 

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di Ọjọruu ọsẹ kan naa, alaga APC nipinlẹ Ogun, Oloye Derin Adebiyi, ti kede pe ko sohun to jọ bẹẹ. O ni ko sẹni to le tu awọn ka, ere lasan ni Oshimohole n ṣe.

 

Oshimohole atawọn ikọ rẹ gbe igbesẹ ile tituka naa pẹlu alaye ti wọn ṣe l’Abuja, pe nnkan ko le maa lọ bo ṣe n lọ yii nipinlẹ Ogun ati Imo.

 

Wọn ni awọn gomina mejeeji, Ibikunle Amosun ati Rochas Okorocha, n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ mi-in ti wọn ti fa aṣoju kalẹ, wọn waa fi ara wọn di gẹrẹwu sinu APC bii pe ọmọ egbẹ toootọ ni wọn. Iwa yii tako ofin jijẹ oloṣelu to fẹran ẹgbẹ ẹ, wọn ni ẹni to yẹ ki ẹgbẹ fofin de awọn gomina yii.

 

Lati ma jẹ ki wọn maa gbe inu ẹgbẹ naa ba ẹgbẹ jẹ ni wọn ṣe ni awọn tu igbimọ to n ṣiṣẹ lọwọ lawọn ipinlẹ meji yii ka. Oshiomhole atawọn ọmọ ẹgbẹ l’Abuja si ni igbimọ NWC yoo ri si bi wọn yoo ṣe yan awọn mi-in ti yoo mojuto idibo ọdun to n bọ.

 

Igbesẹ yii ni Alaga APC nipinlẹ Ogun, Oloye Derin Adebiyi, tako ninu atẹjade to fi sita l’Ọjọruu, nibi to ti ṣalaye pe oun atawọn ọmọ igbimọ oun ṣi wa lọfiisi awọn digbi nipinlẹ yii, bẹẹ lawọn n ba iṣẹ oṣelu lọ lai jẹ pe kinni kan di awọn lọwọ.

 

Oloye Derin ni eremọde lasan ni alaga apapọ ẹgbẹ awọn n ṣe.

 

Alaga ẹgbẹ Onigbalẹ nipinlẹ Ogun naa ṣalaye pe ẹjọ ṣi wa ni kootu, l’Abuja, niwaju Adajọ Jude Okeke, nitori awọn ti sa di kootu nigba tawọn ti ri ọwọ ọdalẹ ti alaga apapọ naa n gbe, awọn ko fẹ ko fọwọ ọla gba awọn loju lo jẹ kawọn tete pe ẹjọ lori ẹ.

 

Atẹjade naa tẹsiwaju pe iwa aibọwọ fun ile-ẹjọ lawọn ka igbesẹ Oshiomhole yii si, ati titapa sofin Naijiria.

 

Wọn ni eyi fi han bi alaga awọn ṣe n ṣi agbara rẹ lo, to n tapa sofin. Oloye Derin atawọn igbimọ ẹ ni ko si ootọ kan ninu ẹsun ṣiṣe oju meji ti wọn fi kan awọn ati Amosun, wọn ni ọmọ APC ṣi lawọn tọkan-tọkan.

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.