Ẹni to ba ṣe bẹẹ yẹn gbọdọ jiya, iya gidi

Spread the love

Igbakeji aarẹ orilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, wa ni ipinlẹ Ekiti lọsẹ to kọja, ẹẹmeji lo lọ sibẹ, laarin wakati mẹrinlelogun sira wọn. Iyẹn ni pe o wa nibẹ loni-in, o pada si Abuja, nigba to si tun di aarọ ọla, o ti tun sare de. Ohun to ṣẹlẹ ni pe nigba ti Ọṣinbajo kọkọ lọ sibẹ, niṣe lo lọ si ibi ti wọn ti n ṣe kampeeni taara, to si bẹrẹ si i sọrọ, ti wọn si jo ti wọn lu ilu, ti wọn pariwo ki wọn dibo fun Kayọde Fayẹmi, ti ọkunrin naa si pada si Abuja. Bẹẹ ohun ti eto ijọba sọ ni pe nigba ti olori ijọba, tabi igbakeji rẹ, tabi eeyan pataki ninu ijọba ba lọ si ipinlẹ kan tabi ilu kan, ẹni ti yoo kọkọ ki bo ba debẹ ni ọba ilu naa, ko too lọ sibi eto to yẹ ko ṣe. Ki i ṣe eni, ki i ṣe ana, ti iru rẹ ti n ṣẹlẹ, Ewi Ado ati awọn ọba to ku si ti palẹmọ, wọn n reti pe Ọṣinbajo yoo de ọdọ awọn ki awọn. Afi bi Ọṣinbajo ko ṣe ranti ya nibẹ, lo ba sare wọ baaluu pada lọ si Abuja. Lawọn ara Ekiti ba pariwo, wọn ni wọn ko ri iru eyi ri o, abi ki lo n ṣe Pasitọ Ọṣinbajo yii na, awọn kan si sọ pe Fayẹmi lo foju tẹmbẹlu ọba naa, oun lo sọ pe awọn ọba Ekiti ko jẹ nnkan kan. Iyẹn ni Fayẹmi ati awọn eeyan rẹ gbọ ni wọn sare sọ fun Ọṣinbajo, n loun naa ba si ko si ẹronpileeni, lọjọ keji lo ti tun de, o waa bẹ Ọba Ado ati awọn Ọba Ekiti to ku. Ohun ti gbogbo wa gbọdọ mọ ni pe nitori ibo n bọ ni Ọṣinbajo ṣe sare wa o, bo ba jẹ pe ko si ti ibo ti wọn fẹẹ di ni, yoo ranṣẹ si kabiyesi ko ma binu ni tabi ko ni ki awọn akọwe rẹ lọfiisi kọwe pe oun ko foju pa ọba naa rẹ, o ṣeeṣi ni. Awọn ti wọn n sọ pe Fayẹmi lo ni ki wọn ma lọọ ki ọba naa paapaa, isọkusọ lasan niyẹn, ko sohun to jọ bẹẹ. Ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn ti wọn n ṣeto irin-ajo naa lo ṣe aṣiṣe. Awọn ti o wa ni ọfiisi Igbakeji Aarẹ ti wọn ti kọwe gbogbo ibi to fẹẹ de, ati awọn ti wọn lawọn n ṣeto ipolongo ti wọn ko ranti pe o yẹ ki awọn de ile ọba. Ṣugbọn ki i ṣe pe wọn mọ-ọn-mọ, aṣiṣe lasan ni. Iru aṣiṣe bẹẹ ko waa gbọdọ lọ lai ni ijiya rẹ ninu. Tabi ta ni yoo sanwo ẹronpileeni to gbe Ọṣinbajo lọ to tun gbe e pada? Akoko ti Ọṣinbajo fi n rin kiri yii nkọ, to fi awọn iṣẹ mi-in to yẹ ko ṣe silẹ ti ko ṣe e. Loju awọn eeyan ti ko ba mọ, eleyii ko jẹ nnkan kan, ṣugbọn o ṣe pataki, nitori gbogbo lilọ bibọ Ọṣinbajo, owo ijọba lo n na, koda, yoo tun gba owo pe oun rin irin-ajo wa si Ekiti lẹẹkeji, bo tilẹ jẹ pe o ṣe aṣiṣe ni. Iyẹn lo ṣe jẹ pe ni awọn ilu nla, ko sẹni ti i fi owo ijọba, ẹropileeni ijọba ati awọn ohun-ini ijọba ṣe kampeeni, ẹgbẹ lo n sanwo eto ipolongo gbogbo. Ṣugbọn ni Naijiria, a ti ha sawọn oloṣelu lọwọ, ki Ọlọrun ṣaanu wa lọwọ wọn ni o!

(58)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.