Eni ti won ti mole ni looya fee loo gba sile tawon olopaa fi lu u lalubami n’Ilorin

Spread the love

Agbẹjọro kan, Lukman Ọlanrewaju Bello, lo kabuku lọwọ awọn ọlọpaa teṣan A Division, to wa niluu Ilọrin, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja.
Ọkunrin yii ni wọn sọ pe awọn ọlọpaa to wa nibudo ti wọn ti n kọ awọn ọlọpaa ti wọn ṣẹṣẹ gba sẹnu iṣẹ to wa niluu Ilọrin ya bo lasiko to fẹẹ lọọ gba onibaara rẹ kan ti wọn mu silẹ. Wọn ni wọn na agbẹjọro naa, koda, wọn tun gba aṣọ rẹ, ko too di pe wọn ti i sẹyin kanta.
Ọrọ ọhun ko yọ Alaga ẹgbẹ awọn amofin, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Muhammed Idowu Akande, ati ẹlẹgbẹ rẹ kan, Dokita Ismail Adua Mustapha, silẹ, nitori wọn ṣe awọn naa baṣubaṣu lasiko ti wọn lọ si teṣan naa.
Bello fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe ọkan lara ọga wọn to wa nibi iṣẹlẹ naa lo dẹ awọn agbofinro ti ko ti i gbokun si oun lati lu oun. Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni wọn mu ọkan ninu awọn onibaara oun pe o tapa si aṣẹ irinna oju popo, idi niyẹn toun si fi lọ si teṣan naa lati gba a silẹ. O ni ọkan lara awọn agbofinro ti oun kọkọ ri ko gbọ nnkan ti oun n ba a sọ rara, niṣe lo ni ki oun jade ni teṣan naa. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ‘Mo ṣalaye fun un pe ọrẹ ni awọn lọọya ati ọlọpaa jẹ, ṣugbọn kaka ko gbọ nnkan ti mo n ba a sọ, ṣe lo gba aṣọ mi, ti awọn yooku rẹ si ti n fi idi ibọn gba mi.’ O ni lẹyin naa ni wọn gbe oun sọ sinu sẹẹli.
O ni ọlọpaa obinrin kan pẹlu awọn mi-in tun waa ba oun ninu sẹẹli ti wọn ti oun mọ, ti wọn si da kondo bo oun.
Alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro (NBA), nipinlẹ Kwara, loun yoo pe ẹjọ lori iṣẹlẹ naa, nitori pe ohun ti awọn ọlọpaa ṣe lodi si ofin.
Ṣugbọn, ileeṣẹ ọlọpaa ti fesi ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, nibi ti wọn ti ṣeleri lati ṣewadii iṣẹlẹ naa finni-finni.
Kọmiṣana ọlọpaa, Fafowora Bọlaji Ọlaniyi tako ohun to ṣẹlẹ naa, o si paṣẹ pe ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori ko ni i lọ lai jiya labẹ ofin.

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.