Ẹni ti Suraju ṣoniduuro fun sa lọ, lawọn ọlọpaa ba wọ ọ lọ si kootu

Spread the love

O pẹ ti baba kan, Suraju Igbayilọla, ti maa n gbọ pe ara o ni iwọfa bii onigbọwọ, abaniyawo lara n ni, ṣugbọn ko ye baba naa, afigba to kawọ pọnyin rojọ nile-ẹjọ lo too mọ pe ki i ṣe gbogbo eeyan lo yẹ lati ṣoniduuro fun.

 

Luqman Sodiq lo huwa kan to tako ofin ninu oṣu kẹjọ, ọdun to kọja, idi niyẹn ti awọn ọlọpaa Ataọja Police Station, niluu Oṣogbo, fi mu un.

 

Lẹyin ti wọn gba akọsilẹ rẹ la gbọ pe Suraju, ẹni ọdun marundinlaaadọta, ṣoniduro fun un lọdọ awọn ọlọpaa pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ, ati pe igbakuugba ti wọn ba ti ni ko wa ni yoo maa yọju.

 

Ṣugbọn bi Luqman ṣe bọ lọwọ awọn agbofinro bayii lo ti fẹyin bẹ lugbẹ, nigba ti gbogbo ipa lati wa a ri ja si pabo ni wọn ranṣẹ si Suraju, nigba toun naa si n tẹwọ pẹbẹ ni wọn wọ ọ lọ sile-ẹjọ.

 

Inspẹkitọ Fagboyinbo Abiọdun to jẹ agbefọba sọ pe iwa ti Suraju hu tako abala aadoje din mẹrin ofin ikẹrinlelogun to n gbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Oṣun.

 

Lẹyin ti Suraju sọ pe oun ko jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an ni agbẹjọro rẹ, Tunde Adedokun, ṣeleri fun kootu pe ko ni i sa lọ fun igbẹjọ ti adajọ ba fi aaye beeli silẹ fun un.

 

Onidajọ O.A. Ọlọyade gba beeli Suraju pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ati oniduuro meji ni iye kan naa.

 

Ọlọyade ni ọkan lara awọn oniduuro naa gbọdọ maa gbe lagbegbe ile-ẹjọ. O si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun yii.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.