Ẹni ti Fẹmi ṣoniduuro fun sa lọ, ni wọn ba wọ ọ lọ sile-ẹjọ

Spread the love

Florence Babaṣọla

Aṣe loootọ ni pe ara o ni iwọfa bii onigbọwọ, abanikowo lara n ni. Titi laelae ni Alade Fẹmi, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, yoo maa kabaamọ pe oun ṣe oniduuro fun Ọlabisi Ọpẹyẹmi lọdọ awọn ọlọpaa pẹlu bo ṣe sa lọ. Lasiko to yẹ ki olujẹjọ fara han ni kootu ni wọn ko ri i, oniduuro ni wọn n ba ṣẹjọ bayii.

Agọ ọlọpaa to wa ni Garaaji Ọlọdẹ, nijọba ibilẹ Guusu Ifẹ, lo ti duro fun obinrin naa lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii, ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ.

Nigba ti awọn agbofinro fẹẹ fi Ọpẹyẹmi silẹ lọjọ naa la gbọ pe Fẹmi fọwọ siwee, o si ṣeleri pe nigbakuugba ti wọn ba ti ranṣẹ si i ni yoo maa yọju si wọn.

Ṣugbọn bi wọn ṣe kuro lọdọ awọn ọlọpaa lọjọ naa ni Ọpẹyẹmi ti sa lọ, ti ko si sẹni to gburoo rẹ mọ. Idi niyi ti awọn ọlọpaa fi mu oniduuro rẹ, wọn si taari rẹ lọ sile-ẹjọ lọsẹ to kọja.

Gẹgẹ bi agbefọba, Inspẹkitọ James Ọbalẹtan, ṣe wi, iwa ti Fẹmi hu ni ijiya labẹ abala aadoje o din mẹrin (126) iwe ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Nigba ti olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun ni Adajọ Olukunle Owolawi fi aaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira ati oniduuro kan ni iye kan naa.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.