Ẹni ba wẹwu aṣeju …. owe Fẹmi Gbajabiamila ni

Spread the love

Koda awọn ti wọn fẹran rẹ sọrọ si i. Awọn ti wọn o si fẹran rẹ naa bu u daadaa. Fẹmi Gbajabiamila ni, ọkunrin aṣofin kan to ti lọ sile-igbimọ aṣofin lẹẹmẹrin ọtọọtọ to si lo ọdun mẹrin-mẹrin, to tun ni oun n lọ lẹẹkarun-un, ki gbogbo eeyan jẹ ki oun tun lọ. Gbajabiamila lo firu-fọnna lọdọ awọn eeyan lọsẹ to kọja nigba ti iyawo rẹ n ṣe ọjọọbi, ni wọn ba bẹrẹ si i bu u. Ko si ohun to ṣe ju pe o loun ra mọto olowo nla, mọto ti owo rẹ fẹrẹ to ọgọrun-un miliọnu fun iyawo oun lọ. Ni iyawo rẹ naa ba mura ara ọtọ kan lọjọ naa, nitori lọjọ to n ṣe ọjọọbi ọmọ aadọta ọdun ni. Bi a ba ti yọwọ pe ole lo nile-igbimọ aṣofin Naijiria, ti gbogbo araalu si gba pe awọn aṣofin wọnyi n ji owo wọn ko, ati bi ilu ti ri ti ara n kan gbogbo eeyan, bi eeyan ba lowo lọwọ to ba ra nnkan fun iyawo rẹ, ko sohun to buru nibẹ rara. Ṣugbọn gbogbo wa la mọ pe ole lo nile-igbimọ aṣofin wa, owo buruku ni wọn n ji ko nibẹ, wọn ko si jẹ ki araalu mọ iye to n to awọn lọwọ gan-an. Nidii eyi, oju ole ni gbogbo eeyan fi n wo awọn aṣofin yii, bi wọn ba ri owo kan lọwọ wọn, wọn yoo ro pe wọn ji i ni. Ẹnikẹni to ba waa gba iṣẹ ilu, to n ṣe oṣelu, to si jẹ awọn araalu ni wọn n sanwo oṣu fun un bii ti Gbajabiamila yii, bo ti wu ki inu rẹ dun to, o loju awọn ohun to le ṣe. Koda, ko fẹran iyawo rẹ ju bayii lọ, o loju awọn ohun to le ṣe fun un. Awọn ara Suurulere ati agbegbe Gbajabiamila ti ebi n pa gidi gan-an ko ni i gbọ pe o fi ọgọrun-un miliọnu ra mọto fun iyawo rẹ ki inu wọn dun si i, wọn yoo ni bo ba ni owo to to bẹẹ lọwọ, ọpọ anfaani wa to le fi ṣe fun adugbo awọn. Bi ilu ba waa ri bayii, bi Gbajabiamila ba tiẹ lowo bẹẹ lọwọ, to si fẹẹ ṣe nnkan funyawo ẹ, ki i ṣe ohun ti yoo pada waa gbe si ori FaceBook ati ẹrọ ayelujara gbogbo. Ṣe iyawo ẹ lo fẹẹ ṣe nnkan fun abi o kan fẹẹ ṣe afẹfẹ-yẹyẹ lasan, ki lo fẹ ki araalu maa sọ nipa oun. Alaye to pada waa ṣe pe oun fẹran iyawo oun ko mọgbọn kan dani, abi ta lo fẹyawo ti ko fẹran tiẹ, ta ni ko si wu ko ra nnkan to daa funyawo ẹ to fẹ sile. Iwa palapala pọ lọwọ awọn oloṣelu, wọn ki i mọ ohun to n ṣe araalu rara, nigba to si jẹ owo ọfẹ, ounjẹ ọfẹ ati mọto ọfẹ lawọn n gun, bawo ni wọn yoo ṣe mọ ohun to n ṣe awọn eeyan gbogbo. Ati pe ṣe eyi ti ọkunrin yii ṣe nile-igbimọ naa ko ti i to ni, ẹẹmẹrin! Ki lo tun n wa lọ sibẹ lẹẹkarun-un! Aṣeju lawọn eeyan yoo pe e, ẹni ba si wẹwu aṣeju, ẹtẹ ni yoo fi ri. Koun naa fa awọn eeyan mi-in kalẹ pe ki wọn waa lọ, ko mu ọmọde mi-in ni adugbo wọn, iyẹn ni yoo jẹ ki wọn mọ pe eeyan daadaa to fẹran awọn eeyan rẹ ni, ti ko si fẹẹ ku sori oye nitori ijẹkujẹ.

(44)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.