“Emi o ki i ṣe ọba ilu Iwo mọ o, Emir ni kẹ ẹ maa pe mi latoni lọ” Ọba Rasheed Akanbi ti ilu Iwo

Spread the love

Ọba Rasheed Akanbi lo sọ bayii lanaa to n fi Sheikh Yakub Adul-Baaqi Muhammed jẹ oye Waziri ilẹ Yoruba. Bo tilẹ jẹ pe ajọ awọn Musulumi ilẹ Yoruba ti kilọ fun Oluwoo titi pe ko fi oye naa mọ niluu ẹ ko ma pe e ni Waziri ilẹ Yoruba, sibẹ Oluwoo ni oun lẹtọ lati feeyan jẹ oye Waziri nilẹẹ Yoruba gẹgẹ bi awọn ọba Hausa ṣe lẹtọ ati ṣe bẹẹ niluu wọn.

Nibi ayẹyẹ naa lo ti sọ pe ki awọn eeyan yee pe oun lọba ilu Iwo mọ, Emir ilu Iwo ni ki wọn maa pe oun gẹgẹ bi awọn Hausa ṣe maa n pe ọba wọn. O ni oun ṣe eleyii lati fi kọṣe awọn ọba Hausa ti ki i ditẹ ara wọn bii awọn ọba ilẹ Yoruba ni. O tẹsiwaju pe ifọwọsowọpọ wọn lo jẹ ki wọn maa dari Naijiria lati ọjọ yii wa, aisowọpọ awọn ọba ilẹ Yoruba lo jẹ ki wọn wa nipo ẹyin, oun ko si fẹẹ farawe wọn.

(79)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.