Emi ati oko mi ti n palemo fun odun keresi ki won too yinbon pa a__ Iyawo oṣiṣẹ LASTMA ti wọn pa

Spread the love

Alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, ni Ọga agba Ajọ LASTMA, Ọgbẹni Chris Olakpe, ati Adari ajọ naa, Ọlawale Musa, ko awọn lọgaa-lọgaa ni ajọ naa lọọ ṣabẹwo ibanikẹdun si iyawo ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun ti ọlọpaa F-SARS yinbọn pa, Rotimi Adeyẹmọ, lọsẹ to kọja. Alukoro ajọ naa, Mamood Hassan, fi iroyin naa to wa leti pe ajọ yii ti ṣe ipinnu lati da ajọ kan silẹ lorukọ oloogbe yii.

Adugbo Ipaja-Ayọbọ, nile oloogbe naa, nibẹ si ni Abilekọ Ẹniọla Adeyẹmọ ati awọn ọmọ rẹ wa. Ọmọ mẹta, eyi ti ibeji wa ninu wọn ni Rotimi fi saye lọ.

O ṣalaye pe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni oun ati ọkọ oun ṣi jọ sọrọ lori eto ti awọn maa fi yọ ayọ ọdun Keresimesi. O ni Rotimi nigbagbọ pe laipẹ loun yoo di olokiki laarin awọn oṣiṣẹ Ajọ LASTMA, nitori ẹmi ifara-ẹni-jin ti oun fi n ṣiṣẹ. Ẹniọla ni ọkọ oun ko mọ pe oun ko ni i wọ inu oṣu yii rara. Obinrin naa sọ pe ọna ti iya ko fi ni i jẹ awọn ọmọ oun lo jẹ oun logun bayii, nitori Rotimi ki i fọrọ wọn ṣere rara nigba aye rẹ. O ṣapejuwe ọkọ rẹ gẹgẹ bii oloootọ eeyan, ẹni to maa n gba awọn eeyan niyanju lati ma ro ara wọn pin.

Ọkan ninu awọn aburo oloogbe, Olurẹmi Adeyẹmọ, sọ pe ka ni oun mọ pe ẹgbọn oun maa ku ni, oun ko ba ti sọ fun un ko fi iṣẹ naa silẹ. O ni oun kọja nibi to ti n ṣiṣẹ niṣẹju diẹ ṣaaju asiko to ṣalabapade iku rẹ naa, ti awọn si ki ara awọn, oun ko mọ pe igba ikẹyin tawọn maa rira niyẹn.

Lasiko ti ọga ajọ naa, Olakpe, n gba iyawo oloogbe yii niyanju, o ni ajọ naa ti n gbe igbesẹ lati ri i pe awọn ṣefilọlẹ ajọ kan lorukọ rẹ ti yoo maa fun awọn oṣiṣẹ LASTMA to ba tayọ lami-ẹyẹ, ki orukọ ati iṣẹ takun-takun ti Rotimi ṣe ma baa parun. O fi kun un pe o ti di oṣiṣẹ ajọ naa meji ti wọn ti ṣeku pa bayii, orukọ awọn mejeeji lawọn yoo si fi ami-ẹyẹ naa sọri.

Rotimi fi awọn obi rẹ mejeeji, ti wọn ti le lọgọrin ọdun saye lọ.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lagbegbe Iyana-Ipaja. Ṣe ni Rotimi, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta, da oṣiṣẹ SARS kan to wa ọkọ Toyota Highlander SUV ti nọmba rẹ jẹ LSR 277 BJ, niwakuwa tako ofin irinna duro. Eyi lo bi Inspẹkitọ Olukunle ninu to fi sọkalẹ ninu ọkọ rẹ, to si lọọ ba Rotimi. Nibi ti wọn ti n fa ọrọ naa ni ọlọpaa SARS yii ti fa ibọn yọ, to si yin in lu oṣiṣẹ LASTMA ọhun.

Nitori pe Olukunle ko wọṣọ ọlọpaa lasiko to fi yinbọn yii, awọn eeyan ro pe ole ni i. Wọn ko fi akoko ṣofo ti wọn fi bẹrẹ si i lu u. Awọn ọlọpaa to n kọja lọ ni wọn ri i, ti wọn si doola rẹ, ṣugbọn o pada jade laye nibi to ti n gba itọju lọsibitu latari lilu ti awọn eeyan lu u.

Bo tilẹ jẹ pe o ti ku, sibẹ Edgal ti paṣẹ pe ki wọn ba oku rẹ ṣẹjọ (Posthumous orderly trial), ki wọn si yọ ọ lẹnu iṣẹ ọlọpaa.

 

Ọdun 2016 ni Rotimi darapọ mọ Ajọ LASTMA

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.