Emeka lu jibiti, lo ba balẹ si kootu l’Ekoo

Spread the love

Kootu ilu Ọgba, nipinlẹ Eko ni awọn ọlọpaa wọafurasi ọdaran kan, Emeka Obiora, lọ. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o lu Friday Augustine ni jibiti. Gẹgẹ bi wọn ṣe ṣalaye ni kootu, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corrolla ni Emeka ṣeleri pe oun aa ba Friday ra, o si ti gba idaji miliọnu Naira lọwọ rẹ gẹgẹ bi owo asan-silẹ.
Lati igba ti Emeka ti gba owo ni awọn ọlọpaa ni ko ti gbe ipe olupẹjọ naa mọ, ko too di pe ọwọ waa pada tẹ ẹ.
Ọkunrin naa loun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun yii, ati pe inu oṣu yii ni oun yoo gbe ọkọ naa fun un.
Ẹsun pipurọ gbowo ati ole jija ni wọn fi kan an, eyi to ni oun ko jẹbi rẹ.
Adajọ kootu naa, Y.O Aje-Afunwa, faaye beeli ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira silẹ fun Emeka, o ni ko wa eeyan meji to le ṣoniduuro rẹ wa.
Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, lo ni igbẹjọ rẹ yoo maa tẹsiwaju

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.