Ẹlẹwọn mẹsan-an gba itusilẹ niluu Eko

Spread the love

Adajọ agba ipinlẹ Eko, Onidaajọ Ọpẹyẹmi Oke, ti tu awọn ẹlẹwọn mẹsan-an silẹ, to si tun paṣẹ fun awọn adajọ pe ki wọn maa gbiyanju lati fi iya ti ko ni i la a n ti afurasi ọdaran mọle lọ jẹ awọn ti wọn ba ṣẹ sofin, ki ọgba ẹwọn ma baa kun akunfaya.

Gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ Naijiria, (NAN), ṣe jabọ, ọkan lara wọn ni Saidi Raimi lati ipinlẹ Kwara, ẹni ti wọn ni o larun ọpọlọ, to si jẹ pe lẹsẹkẹsẹ ti wọn tu u silẹ naa ni wọn ti gbe e lọ si ọsibitu awọn to n ri si arun ọpọlọ.

Mẹrin ninu awọn ti wọn tu silẹ naa ni wọn ti lo ọdun mẹjọ si mọkanla lọgba ẹwọn. Wọn ni wọn ti lo iye ọdun to yẹ ki wọn lo lẹwọn ka ni kootu da wọn lẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, ṣugbọn niwọn igba ti ko si ile-ẹjọ to da wọn lẹbi, Onidaajọ Ọkẹ yọnda wọn. O kilọ fun awọn to gba ominira naa lati huwa ọmọluabi lawujọ, ki wọn si ma tun rin ni bebe ẹwọn.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.