Eletekete ni Yayi, o n leku meji, yoo pofo

Spread the love

Bi eeyan ba n wa oloṣelu ti etekete ati agabagebe fọ lori ati nifun, bo ba ti ri ọkunrin ti wọn n pe ni Solomon Adeọla Yayi, ko jokoo sọdọ ẹ ko ma tun wa ẹlomi-in lọ mọ, ete buruku wa lagbari rẹ, ko si fi bo pe oun ko tori ilu ṣe oṣelu, nitori ohun toun yoo jẹ loun ṣe n kiri. Ọsẹ to kọja yii ni ọkunrin naa ṣeto awọn kan ti ebi n pa, awọn ti wọn yoo gba wan-wan taosan, awọn ti wọn yoo fun ni ẹgbẹrun kan tabi ẹgbẹrun meji Naira, ni wọn ba n pariwo kiri Alimọṣọ, wọn ni Adeọla Yayi lawọn fẹ ko tun waa lọọ ṣoju awọn nile-igbimọ aṣofin. Ko si ẹni ti aye rẹ bajẹ bii ẹni to ri ẹni to n ba a laye jẹ to tun n ba a ṣọrẹ, ṣebi tọhun yoo maa ba aye rẹ jẹ si i ni. Awọn oloṣelu bii awọn Adeọla yii n ba aye awọn eeyan jẹ ni, ṣugbọn ko ye awọn ti wọn n ba laye jẹ. Lati bii ọdun mẹta sẹyin lọkunrin yii ti n ṣe iṣẹ loju mejeeji, to n kiri ipinlẹ Ogun ni tọsan toru, to n ko awọn eeyan jọ, to si n sọ fun wọn pe oun loun fẹẹ waa ṣe gomina wọn ni ọdun 2019, nitori ọmọ Yewa loun. Awọn ara agbegbe naa bẹrẹ si i sare tẹle Yayi lẹyin, ki i ṣe nitori owo to n fun wọn, ṣugbọn nitori awọn araabẹ ti fẹ ki ọmọ wọn kan waa ṣe gomina ipinlẹ Ogun, ṣe ọmọ Yewa kan ko i ti i ṣe gomina wọn ri. Yayi fi wọn lọkan balẹ nigba ti awọn kan n bi i pe ṣe ko ni i sa pada si Eko ti yoo fi awọn sinu agbami. Ọkunrin naa ni ka ma ri i, o ni gbogbo ohun to yẹ ki oloṣelu ṣe ni ipinlẹ Eko loun ti ṣe, oun ti ṣe sẹnetọ, oun ti ṣe aṣoju-ṣofin, ko tun si ohun to ku ti oun tun fẹẹ ṣe ni ipinlẹ Eko, nitori oun ti sin wọn to, asiko niyi lati waa sin awọn eeyan ipinlẹ toun, ipinlẹ Ogun. Ogunlọgọ awọn eeyan ni wọn n sare tẹle e lẹyin, nitori wọn nigbagbọ ninu rẹ gan-an. Ṣugbọn nigba ti ọkunrin yii ri i pe yoo ṣoro foun lati di gomina lasiko yii, ko le fi ọdun mẹrin mi-in silẹ ko fi ṣe iṣẹ rẹ bii iṣẹ, ko fi kiri, ko si lọ sọtun-un sosi, ko fi ẹsẹ ara rẹ mulẹ ki ibo mi-in too de lọdun 2023, niṣe lo sare pada wa si Eko to n bẹ kiri. Ko too debẹ, awọn aṣaaju APC ti n wo ẹlomiiran ti yoo lọ si ile-igbimọ aṣofin agba, ẹni ti yoo rọpo rẹ. Iyẹn lo ṣe sare ko awọn kan jọ, ti awọn yẹn n jo ijo oponu kiri, ti wọn ni Yayi lawọn fẹ. Awọn yẹn ko mọ ohun to n lọ o, wọn ko mọ idi ti Yayi ṣe n ṣe saraa ọsan gangan, wọn ko mọ pe ẹbọ ki iku oṣelu ma pa a lo waa ru, iyẹn lawọn fori gbe ti wọn yoo si maa ru kiri. Ẹni ba fori ru iru ẹbọ bẹẹ, oṣi ni i ta wọn, iyẹn ni gbogbo ọlọgbọn ṣe gbọdọ ṣọra fun saraa jijẹ. Yayi fẹẹ ku iku oṣelu, nitori awọn aṣaaju APC ko fẹ ko tun lọ sile aṣofin lorukọ ẹgbẹ wọn mọ, nigba to ti ni ọmọ Yewa loun, oun ki i se ọmọ Alimọṣọ, gomina Ogun loun fẹẹ ṣe. Ọkunrin naa ti le eku meji, ko si ko ma pofo. Ṣugbọn ko fẹẹ pofo, iyẹn lo ṣe n pe awọn araalu ni ọdẹ, to n tan wọn, to ro pe wọn ko mọ ohun ti oun n ṣe. Eletekete oṣelu niyi, bi ete ati arekereke eeyan kan ba si ti pọju, ohun ti yoo pada ṣe e leṣe naa niyẹn! Ẹ sọ fun Yayi ko mura si i, yoo ba ẹru rẹ nibode!

(51)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.