Ekiti yoo bẹrẹ si i pese ounjẹ fun Naijiria laipẹ–Fayẹmi *Bẹẹ nijọba fẹẹ kọ ileewe imọ ijinlẹ ati papakọ ofurufu Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ti ṣeleri pe ipinlẹ Ekiti yoo bẹrẹ si i pese ounjẹ fun ilẹ yii laipẹ, pẹlu bi ijọba yoo ṣe gbaruku ti awọn agbẹ lọna igbalode.
O sọ eyi di mimọ lopin ọsẹ to kọja nigba to ṣabẹwo si aka nla tileeṣẹ National Food Reserves Agency kọ siluu Ado-Ekiti, nibi ti wọn yoo maa ko ounjẹ pamọ si. Aka yii lo jẹ iwoye ijọba apapọ lati maa pese ounjẹ fun ilẹ yii lasiko ti awọn agbẹ ko ba ni ere oko kankan pẹlu bi wọn yoo ṣe maa ta eyi ti wọn ti ko pamọ.
Fayẹmi ṣalaye pe Ekiti lagbara lati bọ gbogbo ilẹ Naijiria tijọba ba pese awọn nnkan tawọn agbẹ yoo maa lo lati dako lọpọ yanturu, paapaa ibi ti wọn yoo maa ko awọn ire oko naa si.
‘’Ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ awọn agbẹ ati idagbasoke igberiko ti ṣetan lati fun awọn to fẹẹ maa ṣakoso aka yii laṣẹ, ireti si wa pe gbogbo eyi yoo wa si imuṣẹ laipẹ. A maa ṣe koriya fawọn agbẹ wa ki wọn le lo anfaani yii daadaa.
Bakan naa ni Fayẹmi ti ṣeleri lati kọ ileewe kan ti yoo jẹ fun iwadii imọ ijinlẹ, nibi tawọn eeyan yoo ti maa kọ ju ẹkọ inu iwe lọ.
Gomina naa ṣabẹwo sibi tijọba n gbero lati kọ ile-ẹkọ naa si loju ọna Ado-Ekiti si Ijan-Ekiti, nibẹ lo si ti sọ pe nnkan tipinlẹ naa nilo lasiko yii niyẹn.
‘’Laipẹ, ọgbọn iwe lasan ko ni i wulo mọ, nitori awọn iṣoro ta a ni nilo ọgbọn atinuda. Gbogbo ibi ni wọn ti mọ wa pe a ni imọ, nigba ti ọpọlọ iwe nikan ko ba si to mọ, awa naa lo yẹ ka jẹ aṣiwaju ninu imọ atinuda.
‘’ Bakan naa la n woye pe papakọ-ofurufu yoo daa lagbegbe naa, ki nnkan le rọrun fun gbogbo ẹni to ba ni nnkan lati ṣe nibẹ.’’
Fayẹmi waa ṣeleri pe gbogbo eto wọnyi ni yoo bẹrẹ ni kete ti iwadii ati agbeyẹwo ba pari.

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.