Ekiti sanwo osu oṣiṣẹ pẹlu owo Paris Club

Spread the love

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ si i sanwo awọn oṣiṣẹ ati oṣiṣẹ-fẹyinti pẹlu owo iranwọ Paris Club bayii lẹyin ti Gomina Kayọde Fayẹmi ti sọ pe ni kete toun ba gba a lawọn oṣiṣẹ yoo gbowo wọn.

Nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja ni Yinka Oyebọde to jẹ akọwe iroyin gomina kede ọrọ ọhun pe Ekiti ti gba biliọnu mẹta ati ẹẹdẹgbẹrun miliọnu (3.9b), Naira lẹyin tijọba apapọ yọ biliọnu mẹta ati ọọdunrun miliọnu (3.3b) ti Ekiti jẹ laarin ọdun 2016 si 2018.

Owo tijọba gba yii ni Fayẹmi paṣẹ pe ki wọn fi san owo awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, awọn oṣiṣẹ ipinlẹ, awọn tiṣa atawọn oṣiṣẹ-fẹyinti.

Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ti bẹrẹ iṣẹ lori abajade iwadii tawọn igbimọ oluwadii ileewe ati ileewosan gbe fun un lọsẹ to kọja.

Awọn igbimọ naa ti wọn bẹrẹ iṣẹ ni bii oṣu meji sẹyin, ti wọn si waa jabọ fun gomina ni ti Ekiti State University (EKSU), Ado-Ekiti; College of Education, Ikere –Ekiti; College of Health Science and Technology, Ijero-Ekiti; ati Ekiti State University Teaching Hospital (EKSUTH).

Nibi eto naa ni gomina ti ṣalaye pe awọn igbimọ yii ko ṣewadii lati fiya jẹ ẹnikẹni, bi Ekiti yoo ṣe tẹsiwaju niṣẹ tijọba gbe le wọn lọwọ. O ni ofin ti wọn fi da awọn ileewe ati ileeṣẹ yii silẹ faaye gba iru awọn iwadii wọnyi lọna ati mọ bi nnkan ṣe n lọ, ati ọna abayọ sawọn iṣoro to wa.

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.