Ẹgbẹrun meji Naira ni Rẹfurẹndi Ezuma maa n fun awọn ọmọkunrin to n ba lopọ

Spread the love

Oludasilẹ ijọ Jesus Intervention Household Ministry, to wa l’Ejigbo, Rẹfurẹndi  Prince Chizemdere Ezuma, lo ti ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe ẹgbẹrun meji Naira loun maa n fun awọn ọmọkunrin toun ba ba sun lẹyin ti awọn ba jọ gbadun ara awọn gẹgẹ bii owo iṣẹ. Ọsẹ to kọja lọwọ ọlọpaa tẹ Ezuma, ẹṣẹ ti wọn lo ṣẹ ni pe o n fipa ba awọn ọmọkunrin sun, o si tun ko arun eedi ran wọn.

Lẹyin ti ọwọ tẹ ekeji rẹ ti wọn jọ maa n ṣiṣẹ ibi naa, Prince Chincherem, ni ọmọdekunrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan tun ṣalaye bo ṣe jẹ pe ọrẹ Prince kan naa tun maa n hu iru iwa yii, eyi lo si jẹ ki awọn ọlọpaa maa dọdẹ rẹ titi tọwọ wọn fi tẹ ẹ.

Ile Ezuma to wa l’Ejigbo, ni awọn ọlọpaa lọọ ka a mọ. Gẹgẹ bi alaye ti awọn agbofinro naa ṣe, wọn ni ṣe ni afurasi ọdaran yii sa gun aja ile rẹ lọ nigba ti awọn kan sọ fun un pe awọn ọlọpaa ti de. Wakati meji ni wọn fi wa a kiri, ki wọn too kẹẹfin rẹ lori aja ile naa.

Awọn ọlọpaa sọ pe ọmọdekunrin naa lo ṣalaye bo ṣe jẹ pe Ezuma maa n gbe awọn fun awọn baba olowo kan ti wọn gbadun ibasun onifurọ. Ọrọ to sọ yii ni wọn fi lọọ ṣayẹwo fun ọmọ naa, ọsibitu ni wọn si ti mọ pe ọmọ naa ti ko arun eedi.

Nigba to n jẹwọ fun awọn ọlọpaa, Ezuma sọ pe ẹgbẹrun meji Naira loun maa n fun awọn ọmọ naa lẹyin toun ba ba wọn sun tan, o ni oun kọ mọ pe oun ni arun eedi lara rara.

Awọn ọlọpaa ti ni laipẹ lawọn yoo wọ ọ lọ si kootu.

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.