Ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin lo fẹẹ dibo l’Ekiti

Spread the love

Lọwọlọwọ bayii, awọn oludibo to le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin lo ti wọ inu iwe ajọ eleto idibo (INEC) ti wọn si laṣẹ lati kopa ninu ibo gomina ti yoo waye loṣu keje, ọdun yii.
Gẹgẹ bi alaye ti alaga ajọ ọhun nipinlẹ Ekiti, Ọjọgbọn Abdul
Ganiyu Ọlayinka Raji, ṣe lọsẹ to kọja, awọn to le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (513, 000) lo ti gba kaadi idibo wọn, ṣugbọn o ṣi ku bii ẹgbẹrun lọna okoolenigba (221, 000) ti ko ti i waa gba tiwọn, ṣugbọn ti wọn lẹtọọ lati dibo.
Ṣe lọsẹ to kọja ni Ọjọgbọn Raji kede ibẹrẹ eto idibo ọdun yii gẹgẹ bi ofin idibo orilẹ-ede yii ṣe sọ pe INEC gbọdọ kede pe ibo fẹẹ waye laarin aadọrun-un ọjọ si ọjọ idibo gangan.
Alaga naa waa sọ pe iforukọsilẹ fun kaadi idibo ṣi n lọ lọwọ, kawọn eeyan lọ si awọn wọọdu ati ijọba ibilẹ wọn lati ṣe ohun to yẹ. Bakan naa lo ni igbaradi gidi ti bẹrẹ fawọn oṣiṣẹ ti ajọ naa fẹẹ lo lọjọ idibo, ki gbogbo eto le waye nirọrun.

O ṣekilọ fawọn ẹgbẹ oṣelu pe gbogbo agbekalẹ awọn ni ki wọn tẹle nitori awọn ko ni i gba igbakugba fun ẹnikẹni to ba tẹ oju ofin idibo mọlẹ.

Laipẹ yii ni ALAROYE gbe eto idibo Ekiti lọdun yii jade, nibi to ti han pe laarin ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, si ọjọ kẹrinla, oṣu to n bọ, ni idibo abẹle yoo waye lawọn ẹgbẹ oṣelu kaakiri, ọjọ kejila, oṣu keje, si ni ipolongo dopin ki ibo gan-an too waye lọjọ kẹrinla, oṣu naa.

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.