Ẹgbẹrun kan ọmọ ẹgbẹ PDP kọyin ṣẹgbẹ l’Ọdẹda, wọn ba APM lọ

Spread the love

Lọjọ Sannde ijẹta yii, ko din lẹgberun kan ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ nijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun, ti wọn kọ ẹgbẹ naa silẹ pe awọn ko ṣe mọ, ti wọn ni ẹgbẹ Onipaki, Allied People’s Movement(APM), lawọn n ba lọ bayii.

Lasiko ti ondije dupo lẹgbẹ APM, Abdulkabir Adekunle Akinlade, n ṣepolongo ibo lati wọọdu kan sikeji lawọn eeyan PDP tẹlẹ naa fi erongba wọn lati darapọ mọ APM han, ti wọn lawọn yoo ṣatilẹyin fun un depo gomina to wu u naa.

Ọgbẹni Adeyẹmi Olufẹmi to ṣaaju awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun yii ṣalaye pe awọn kuro ni PDP nitori ẹgbẹ naa ko ri tawọn ọmọ ẹgbẹ ro, bamubamu ni mo yo lawọn agba ibẹ n ba kiri. Bakan naa lawọn ọmọ ẹgbẹ APM tuntun yii sọ pe awọn gbagbọ ninu Akinlade, wọn lo da awọn loju pe igbesẹ Gomina Ibikunle Amosun ni yoo tẹlẹ, gbogbo iṣẹ ti gomina naa ba si ṣe ku loun yoo pari, ohun tawọn ṣe fẹẹ dibo awọn fun un niyẹn.

Nigba to n fi idunnu rẹ han sawọn eeyan naa, Adekunle Akinlade sọ pe oun ko ni i dojuti wọn, wọn ko si ni i kabaamọ pe wọn darapọ mọ ẹgbẹ oun. O ni fifi ẹtọ ẹni du ni ti wọn ṣe foun ninu APC ko ni i lọ lasan bẹẹ, oun yoo ja fẹtọọ oun ti wọn fi du oun lasiko ibo abẹle ẹgbẹ Onigbaalẹ naa.

Ṣaaju ni Triple A bi wọn ṣe maa n pe e ti sọ pe awọn eeyan ko mọ ohun toju oun ri koun too di ondije dupo gomina. O ni ọpọ eeyan ro pe Amosun kan deede fa oun kalẹ lati dije ni, wọn ko mọ irin toun rin, igbiyanju toun ṣe, koun tiẹ too foju kan Amosun rara. Bẹẹ, ifẹ ilu, erongba lati jẹ ki ọmọ Yewa di gomina Ogun lẹẹkan yii, lo mu oun tẹsẹ bọ ere ije naa lati inu APC, ṣugbọn ti wọn tibi ibo abẹle kọju oun soorun alẹ.

Olu Ọdẹda paapaa kin Akinlade lẹyin, Ọba Ishọla Ọlọrunṣọla sọ fun un pe ko fi ọkan rẹ balẹ. Kabiyesi ni gbogbo Ọdẹda ni yoo dibo fun APM ninu ibo oṣu kẹta, ọdun yii, awọn yoo ṣatilẹyin fun Triple A lati di gomina, o si da oun loju pe yoo wọle.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.