Ẹgbẹ PDP Kwara yoo kede awọn oloye tuntun lọsẹ yii

Spread the love

Bi gbogbo nnkan ba lọ bi wọn ti ṣe ṣeto rẹ, lọsẹ yii lẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara yoo kede awọn oloye tuntun. Aṣofin ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ, Onimọ-Ẹrọ Abdulrauf Kọla Shittu, nireti wa pe yoo rọpo alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Akọgun Iyiọla Oyedepo, gẹgẹ bii alaga tuntun.

ALAROYE hu u gbọ pe lara awọn to tun ***naa tukọ ẹgbẹ PDP ni kọmiṣanna fun akanṣe iṣẹ nigba kan ri, Alhaji Razak Lawal, gẹgẹ bii akọwe ẹgbẹ, ti Hajia Ramat Ọganija naa si gba ipo adari awọn obinrin.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ohun to fa a ti wọn fi mu awọn mẹtẹẹta naa ni adehun to ti wa laarin awọn ikọ ti Saraki ko wọnu ẹgbẹ naa atawọn ti wọn ba nibẹ pe awọn ti Saraki lo maa yan ida ọgọta ninu ipo ẹgbẹ naa, ṣugbọn ida ogoji lawọn to ti wa nibẹ lanfaani lati mu.

Ṣe kete ti Bukọla Saraki pada sẹgbẹ PDP ni alaga ẹgbẹ naa, Akọgun Iyiọla Oyedepo kọwe fipo rẹ silẹ, to si lọọ darapọ mọ APC ti Saraki ti kuro. O loun ko ṣetan lati ba Saraki ṣiṣẹ papọ.

Ọgbẹni Shittu ati Hajia Ọganija ni wọn wa lati igun ti Saraki ko sodi lọ sẹgbẹ PDP, ṣugbọn Razak Lawal ni tiẹ jẹ ọkan lara awọn ti wọn ba ninu ẹgbẹ PDP.

Nibi ipade kan to waye l’ọjọ,  Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni wọn ti fa awọn oloye tuntun naa kalẹ. Gbogbo awọn adari ẹgbẹ to wa nibẹ lo jọ panu-pọ lati fa awọn mẹtẹẹta kalẹ. Ireti wa pe ọsẹ yii ni wọn yoo fẹnu gbogbo ọrọ naa jona ni kete ti ẹgbẹ PDP lapapọ ba ti fun wọn laṣẹ lati tẹsiwaju, ki wọn si kede awọn oloye tuntun naa.

Oriṣiriiṣi ipade lo waye lalẹ ọjọ Sande lati tubọ mu ibaṣepọ to danmọran wa laarin awọn to ṣẹṣẹ wọnu ẹgbẹ naa atawọn ti wọn ba nibẹ.

Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Dokita Ali Ahmad, la gbọ pe o dari ipade naa. Lara awọn to wa nibẹ ni akọwe ijọba,  Alhaji Isiaka Gold; kọmiṣanna tẹlẹ fun eto ẹkọ ati idagbasoke araalu, Alhaji Saka Onimago, atawọn mi-in bẹẹ lọ.

Iwadii fi han pe Saraki atawọn ọmọ ẹgbẹ PDP to ti wa nilẹ tẹlẹ ti fẹnukọ lori bi wọn yoo ṣe pin awọn ipo ẹgbẹ kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ Kwara.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.