Ẹgbẹ oṣiṣẹ fofin de Aluko ati Ọlaiya fọdun mẹwaa

Spread the love

Lẹyin wahala to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja lori iyanṣẹlodi, agbarijọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ekiti ti kede pe awọn fofin de Comrade Ayọdeji Aluko to jẹ alaja Nigerian Labour Congress (NLC), tẹlẹ ati ojugba rẹ ni Trade Union Congress (TUC), Kọlawọle Ọlaiya, fun ọdun mẹwaa.

Nibi ipade to waye nile ẹgbẹ naa niluu Ado-Ekiti lawọn oṣiṣẹ ti Comrade Ade Adesanmi to jẹ alaga NLC lọwọlọwọ ati Ọdunayọ Adesoye ti TUC dari ti ṣepinnu ọhun.

Bakan naa lawọn oṣiṣẹ naa kede pe awọn fọwọ si igbimọ to n dari NLC ati TUC, yatọ si nnkan ti Ọlaiya ati Aluko sọ lasiko ti wọn lọọ le awọn oṣiṣẹ jade ninu ọfiisi wọn lọsẹ to kọja.

Awọn ọmọ ẹgbẹ naa bẹnu atẹ lu iwa awọn adari tẹlẹ naa, bẹẹ ni Adesanmi ke sawọn agbofinro lati wa nnkan ṣe sọrọ wọn ki wọn too da rugudu silẹ l’Ekiti. Wọn ni tọọgi ni wọn n ko kiri lati dẹruba awọn oṣiṣẹ lori iyanṣẹlodi ti wọn ni wọn gbọdọ gun le, bẹẹ wọn ko laṣẹ lati ṣe bẹẹ.

Adesanmi ni, ‘’ Nigba kan ni Gomina Ayọdele Fayoṣe gbe igbimọ iwadii dide nitori Aluko, wọn si sọ pe o jẹbi ẹsun lilọwọ si oṣelu, eyi to tako ofin iṣẹ ijọba. Ẹgbẹ yii kan naa lo da sọrọ ọhun ti wọn fi dariji i.

‘’Ki i ṣe iroyin pe wọn deede gbe Aluko le ori awọn ọga ẹ nijọba ibilẹ to ti n ṣiṣẹ, eyi to mu kijọba ṣagbeyẹwo igbesẹ naa, ti wọn si da a pada. O ti han gbangba pe Aluko n binu gidi, ṣugbọn ṣe ọrọ owo-oṣu tijọba ko san lo yẹ ko fi maa ṣawawi?’’

A gbiyanju lati pe awọn mejeeji tọrọ kan, ṣugbọn aago wọn ko lọ ta a fi pari akọjọpọ iroyin yii.

(40)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.