Ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn yoo yan igbimọ lati wadii ibo gomina Ekiti

Spread the love

Alukoro ẹgbẹ PDP, Kọla Ologbondiyan, sọ lọjọ Sannde ọsẹ yii pe awọn yoo gbe igbimọ kan dide lati wadii idibo gomina ti wọn di lọjọ Satide ti wọn fi yan oludije ẹgbẹ APC, Kayọde Fayẹmi, gẹgẹ bii gomina tuntun ipinlẹ Ekiti, nitori ole ojukoroju lawọn ẹgbẹ APC ja awọn.

Ologbondiyan ni awọn ko gba esi idibo ajọ INEC ti wọn fi ja oludije ẹgbẹ awọn, Ọmọwe Kọlapọ Oluṣọla Ẹlẹka, kulẹ rara, nitori bi eto idibo naa ṣe n lọ ni gbogbo wọọdu ti wọn ti di i lawọn n mojuto, afigba to di pe wọn fẹẹ ko ibo naa papọ ni wọn le awọn aṣoju awọn ti wọn wa nibẹ, ti wọn si ṣe eru ti wọn fẹẹ ṣe.

Kọla ni ọwọ awọn ajọ eleto aabo naa ko mọ nibi ọrọ yii, nitori tibọn-ibọn ni wọn fi n dẹruba awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lati dibo fun APC ni awọn wọọdu kan, eyi to lodi si ijọba awa-ara-wa ti wọn tori ẹ ṣeto idibo yii.

Bẹẹ naa lo ni awọn ẹgbẹ APC lọọ ko ajeji wa lati awọn ipinlẹ mi-in lorilẹ-ede yii lati dibo fun wọn, pupọ ninu awọn ti wọn ka pe wọn dibo fun Fayẹmi ki i ṣe ara Ekiti rara.

Lakootan, Ologbondiyan ni ẹgbẹ awọn ko ni i gba esi awuruju ti wọn gbe jade yii, awọn si ti n ko awọn ẹri awọn jọ lori gbogbo aiṣedeede eto idibo ti wọn ṣe yii, laipẹ, awọn yoo sọ igbesẹ to ba kan lẹyin akojọpọ ti awọn ṣe yii fun gbogbo araalu.

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.