Ẹgbẹ oṣelu PDP ṣabẹwo imoore si agbegbe Oke-Ogun

Spread the love

Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti i ṣe oludije funpo gomina lẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, nipinlẹ Ọyọ, ti ṣabẹwo imoore si agbegbe Oke-Ogun lọsẹ to kọja, nibẹ lo si ti ṣeleri pe oun yoo wa ojutuu si aawọ to wa laarin ẹgbẹ naa ti oun ba di gomina lọdun to n bọ.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja lo sọrọ yii nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP sọrọ ni Gbọngan Ṣaki Parapọ, to wa niluu Ṣaki. Makinde fi aidunnu ọkan rẹ han si ipo ti awọn ọna agbegbe naa wa, ati airiṣe to ti gbilẹ lawujọ.
O waa fi asiko naa dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ lagbegbe Iṣẹyin, Kiṣi, Oorelope ati Irẹpọ, fun atilẹyin ti wọn ṣe fun oun nibi eto idibo abẹle naa. Makinde rọ awọn ọmọ ẹgbẹ pe ki wọn ma jẹ ki ahesọ to n lọ kiri pe awọn kan n kuro lẹgbe PDP l’Oke-Ogun o ba wọn lọkan jẹ, nitori ko si ootọ ninu ọrọ naa rara.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.