Ẹgbẹ NCNC ni ki wọn yọ Awolọwọ jade kuro lẹwọn, l’Akintọla ba binu rangbọndan

Spread the love

Ki i ṣe Hubert Ogunde nikan lo n sọrọ Ọbafẹmi Awolọwọ to wa lẹwọn, o kan jẹ pe oun ni Oloye Samuel Ladoke Akintọla ati ijọba rẹ, pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ NNDP, iyẹn Ẹgbẹ Dẹmọ le fi ikanra mọ ni. Ṣe Adajọ agba ilẹ yii nigba naa, Adajọ Adetokunbọ Ademọla, ti ranṣẹ pe Ogunde, o si ti sọ fun un pe oun ko fẹ ko ṣere “Yoruba Ronu” to fẹẹ ṣe l’Ekoo, nitori laarin awọn asiko to fi ere naa si, to si fẹẹ maa gbe e kaakiri ilẹ Yoruba, asiko naa loun yoo da ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti Awolọwọ pe, oun ko si le faramọ ọn ki oun dajọ lọsan-an, ki Ogunde waa ko awọn eeyan jọ lalẹ, ko maa fi ere tirẹ ṣedajọ Awolọwọ, to jẹ bi oun Ademọla ba ni Awolọwọ jẹbi, oun Ogunde yoo fi ere Yoruba ronu sọ pe Awolọwọ jare. Bẹẹ, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin, ni ẹjọ ti Adetokunbọ Ademọla n sọ yii yoo bẹrẹ o, Ogunde yoo si wa nibi to ti n gbe ere rẹ kiri.

Ipalẹmọ ti n lọ rẹpẹtẹ, awọn adajọ marun-un ni wọn ti gbaradi fun ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti Awolọwọ pe yii, nitori baba olori oloṣelu ilẹ Yoruba naa sọ nigba naa pe bi wọn ṣe ju oun si ẹwọn ko dara, oun ko gba idajọ ti awọn adajọ naa da oun, nitori ẹ loun si ṣe gbe ẹjọ oun wa si ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, ki wọn le ba oun da a. Adajọ Ademọla ti i ṣe adajọ agba fun Naijiria nigba naa ni yoo ṣe olori awọn adajọ ti yoo wa nibẹ lati gbọ ẹjọ yii, oun ni yoo si pada da ẹjọ ọhun lẹyin ti wọn ba ti gbọ ọ tan. Awọn adajọ mẹrin mi-in yoo tun jokoo ti i o: Adajọ Louis Mbanefo ti i ṣe adajọ agba fun Eastern Region, Adajọ Conrad Taylor, pẹlu awọn adajọ oyinbo meji, Adajọ Vahe Bairamian ati Adajọ Lionel Brett. Ko ma di pe boya ọrọ naa ko ni i ye ara wọn, Awolọwọ paapaa ti gba lọọya oyinbo, Victor Durand lorukọ rẹ, oun naa ti de.

Nigba to jẹ ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ni, ti ki i ṣe pe wọn yoo tun jẹ ki awọn eeyan naa rojọ mọ, Awolọwọ funra ẹ ti ni oun ko ni i wa si kootu, nitori oun ko fẹ ki awọn ero waa ya pade oun, kawọn ti wọn n ṣejọba ma tun sọ pe oun waa fi ara oun han ni, tabi pe oun tun fẹẹ gbajọba lọwọ wọn. Ati pe nigba to jẹ ọkan ninu awọn lọọya to gbona lati ilu oyinbo loun gba, to si ti mọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ lai ku eyọ kan, ko si idi ti oun yoo fi tun maa waa garun wo ohun ti wọn n ṣe. Nigba ti a n wi yii, awọn mẹtadinlogun ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ, Action Group (AG), ni wọn ti ju sẹwọn, awọn naa ni wọn si pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun yii. Loootọ awọn alaṣẹ ti fi ọkan Akintọla balẹ pe ọrọ ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti Awolọwọ pe yii, oyun ti bomubomu ba ni ni, atẹgun lasan ni yoo fi bi, ko si kinni kan ti yoo tidi ẹ yọ, sibẹ, ọkan Akintọla funra rẹ ko balẹ, o n ro o pe ọrọ naa le ja si ibi ti oun ko fẹ.

 

Kin ni Akintọla ko si fẹ? Ko fẹ ki Awolọwọ jade lọgba ẹwọn to wa ni. Ko fẹ rara. O mọ pe bi Awolọwọ ba wa laarin ilu, gbogbo ara ti oun n da nile ijọba, ati bi oun ṣe n ri awọn ọmọ ẹyin rẹ ja lọtun-un losi yii ko ni i ṣee ṣe, ọpọ awọn ti wọn si ti n ba oun ṣe tẹlẹ tun le pada lẹyin oun. Awọn araalu gan-an le bẹrẹ si i koriira oun, ti wọn yoo si maa da ijọba oun laamu. Ju gbogbo rẹ lọ, Akintọla mọ pe bi Awolọwọ ba wa nile, ohunkohun lo le ṣẹlẹ, nigba ti ko si mọ ohun to le ṣẹlẹ yii lo fi n sare kaakiri. Gbogbo ọna to mọ lo n tọ, ko ṣa fẹ ki Awolọwọ jade nibi to wa, nitori o mọ pe bo ba jade, yoo di eto oṣelu oun lọwọ. Tẹlẹtẹlẹ ni Akintọla ti n ṣọ ija naa ja, ṣugbọn nigba to ya, o kuku gbe kinni naa soju, o ni ki kaluku sọ ohun to ba fẹẹ sọ.

Asiko yii ni awọn NCNC dide gan-an, paapaa awọn NCNC ti wọn wa ni ilẹ Yoruba ati awọn ti ilẹ Ibo, wọn ni ki wọn fi Awolọwọ silẹ lọgba ẹwọn lo daa. Ṣe bi ọrọ awọn oloṣelu ti ri niyẹn, awọn naa wa ninu ẹni to ran Awolọwọ sẹwọn tẹlẹ, nitori bi ẹgbẹ wọn ko ba ba Akintọla ṣe ni, Akintọla ko le di Prẹmia, ọmọ ẹyin Awolọwọ ni yoo di ipo naa mu, iyẹn Dauda Adegbenro, wọn yoo si ti mọ bi Awolọwọ yoo ti ṣe jade lẹwọn lati igba yẹn. Ṣugbọn awọn NCNC naa ko fẹ ti Awolọwọ, wọn ro pe oun lo n di awọnlọwọ ti ko jẹ ki awọn gbajọba ni Western Region, ati pe bi ko ba si loju-ọpọn mọ, awọn yoo mọ bi awọn yoo ti ta ayo ti awọn yoo si jẹ. Ohun to jẹ ki wọn wa lẹyin Akintọla ti ọkunrin naa fi gbajọba ree. Igba to waa gbajọba tan, to yi kadara wọn pada, to si sọ ẹgbẹ naa di korofo ni West, nigba naa ni wọn mọ pe Awolọwọ daa ju Akintọla lọ, ni wọn ba n pariwo pe ki wọn yọ ọ jade kuro lẹwọn.

Ni ile igbimọ aṣofin apapọ l’Ekoo ni Ọjọ Jimọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 1964, ọmọ ẹgbẹ NCNC kan dide, E. A. Mordi lorukọ rẹ. Ọrọ lori eto owo nina ọdun naa ni wọn n sọ, ṣugbọn o kan ya bara lojiji ni, lo ba ni oun fẹẹ sọrọ kan to ṣe pataki. O ni ki gbogbo awọn aṣofin ti awọn jokoo ma ṣe ro pe alaafia wa ni Western Region o, o ni ko si alaafia nibẹ, ko si si ohun to fa a ti ko ṣe si alaafia nibẹ ju pe Awolọwọ wa lẹwọn lọ. O ni bi awọn aṣofin yii ba n tan ara wọn jẹ nikan ni wọn yoo sọ pe awọn ko mọ pe Awolọwọ ni aṣaaju awọn Yoruba, ati aṣaaju oloṣelu Western Region, nigba ti Awolọwọ ko si si nile mọ, ti awọn kan wa n fi tipatipa fun awọn eeyan ni aṣaaju lo n da wahala silẹ,nitori aṣaaju ti wọn fun wọn o tẹ wọn lọrun, aṣaaju kan ṣoṣo naa ti wọn mọ, ti wọn si fẹ, ni Ọbafẹmi Awolọwọ.

O ni ọrọ pe wọn n pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, wọn n lọ, wọn n bọ, lori ẹjọ ati lọọya, ati awọn oriṣiiriṣii agbelẹrọ awọn eto ti wọn n ṣe lori ọrọ yii, pe awọn ọlọgbọn ti mọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si, wọn mọ pe bi wọn ṣe e di ọtunla mẹwaa, Awolọwọ ko ni i jade lẹwọn bi ki i baa ṣe pe ijọba yii fẹ ko jade. Nitori bẹẹ, o ni ki ẹnikẹni ma fi akoko ilu ati ijọba ṣofo, ki wọn fi Awolọwọ silẹ ko maa ba tirẹ lọ. Ọrọ naa da nnkan silẹ ni ile igbimọ aṣofin, nitori bi oun ti n sọrọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC pupọ n sọ pe ootọ lo n sọ, ọrọ rẹ daa, bẹẹ ni awọn mi-in bẹrẹ ariwo gidi, awọn ọmọ ẹgbẹ NPC, ẹgbẹ awọn Sardauna, ati awọn ọmọ ẹgbẹ NNDP, ẹgbẹ Dẹmọ, ẹgbẹ awọn Akintọla. Niṣe ni wọn bẹrẹ si i pariwo “Noo! Noo! Noo!” bo tilẹ jẹ pe Mordi ko ṣe bii ẹni pe oun gbọ wọn, o n ba ọrọ rẹ lọ ni, o si pari ọrọ naa pẹlu pe bi wọn ko ba fi Awolọwọ silẹ, wahala gidi yoo ṣẹlẹ, ti yoo kan gbogbo Naijiria o.

Boun ti jokoo lọkunrin kan sare dide, Damale Kaite, ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ NPC, ọmọlẹyin Sardauna ni. O ni oun naa fẹẹ ya bara ni o, oun fẹẹ lo akoko naa lati ki eeyan pataki kan ni orilẹ-ede Naijiria ku oriire, oun si fẹ ki gbogbo awọn ọmọ aṣofin ba oun ki i bẹẹ. O ni ẹni naa ni Oloye Samuel Ladoke Akintọla, o ni oun fẹẹ ki i ku oriire ti Ẹgbẹ Dẹmọ to da silẹ, nitori oun mọ pe ẹgbẹ ti yoo gba gbogbo ọmọ Yoruba la ni, ẹgbẹ ti yoo sọ awọn ọmọ Yoruba di eeyan pataki ni Naijiria, ti yoo si ṣe gbogbo rere ti wọn ba n reti fun wọn. O ni ki awọn aṣofin ma jẹ ki ẹnikẹni tan wọn, alaafia ti de si West, ẹgbẹ ti Akintọla da silẹ ni yoo si mu alaafia naa wa, ki gbogbo awọn eeyan kan fọwọ sowọ pọ pẹlu ẹ naa ni. Bo ti sọ bẹẹ lo fidi kalẹ.      

Ohun to waa ṣẹlẹ ni pe bi oun naa ti n sọrọ lawọn kan ṣe “Noo! Noo!” ti awọn mi-in si n ṣe “Yẹẹsi! Yẹẹsi!” Ṣe ọrọ ile aye yii, bii ilu gangan ni, bo ba kọju sẹni kan, yoo kẹyin si ẹlomi-in, ṣugbọn ẹni to kọju si yoo ni oju lo kọ soun, ẹni to kọyin si naa yoo tun ni oju lo kọ soun. Ounjẹ ti ẹni kan n sọ pe oun ko fẹ, oun ko ni i ki i bọ ẹnu oun laelae, ounjẹ naa lẹlomiiran yoo maa pọn ẹnu la nitori ẹ, to si jẹ bi wọn ko ba fun un jẹ, biliisi gidi ni. Awọn kan fẹ ki wọn fi Awolọwọ silẹ lọgba ẹwọn, ko jade, ki alaafia le wa si West, awọn kan ni awọn ko fẹ, wọn ni jijade Awolọwọ yẹn gan-an ni ko ni i jẹ ki alaafia wa nibikibi ni Naijiria. Bi Akintọla atawọn eeyan tirẹ ti n ronu niyẹn, wọn si ti gbe ọrọ naa de eti Sardauna, oun naa si ti fọwọ si i pe ko si ohun ti Awolọwọ fẹẹ waa ṣe nita, ko wa nibi ti wọn fi i pamọ si, ko maa ṣoṣelu ẹ nibẹ.

 

 

 

Inu Akintọla ko tilẹ dun rara pe ọrọ Awolọwọ tun di iru ariwo ti wọn tun bẹrẹ si i pa yẹn. Ṣebi o ti wa lẹwọn, ki lo waa yẹ ko tun fa wahala, nigba ti agbara nla ti wa lọwọ awọn. Awọn yoo ba gbogbo awọn ọmọlẹyin rẹ sọrọ, awọn yoo si ko wọn mọ inu ẹgbẹ awọn, eyi to ba si taku ti ko gba, awọn yoo fi ipa gidi mu un debii pe ko ni i si ohun ti yoo ṣe ju ko ba awọn ṣe lọ, bi bẹẹ kọ, ẹwọn loun naa yoo ti maa ṣe oṣelu tirẹ bii ọga rẹ, ko ju bẹẹ lọ. Ohun ti oun Akintọla n ro niyẹn, o ti ro pe pẹlu gbogbo agbara to wa lọwọ oun yii, ko tun si ẹnikan to yẹ ko maa royin tabi pariwo Awolọwọ mọ, nitori ko si ohun ti Awolọwọ fẹẹ ṣe fun wọn ti oun ko le ṣe. Nibi ti ọrọ naa ka a lara de, Akintọla jade sita ni ọjọ kẹta, oṣu kẹrin, ọdun 1964, o si sọrọ si Awolọwọ lori redio ati tẹlifiṣan debii pe gbogbo eeyan lo n beere pe ṣe nnkan mi-in tun ti de ni.

Ṣe araalu ko mọ ohun to n lọ, awọn ko mọ pe ija n lọ laarin awọn oloṣelu, ti ọrọ naa si ti di nnkan ti ko fi ọkan Akintọla balẹ mọ. Oun n ro pe bi ariwo naa ba pọ ju, o ṣee ṣe ki awọn eeyan kan bẹrẹ si i da Sardauna laamu, ki wọn si sọ fun un ko fi Awolọwọ silẹ. Ṣe bi Sardauna ti wa lẹyin Akintọla to, to si jẹ oun ni ile agbara rẹ, awọn kan ninu ẹgbẹ toun naa ko faramọ ohun to n ṣe, awọn naa n ba a ja pe ko dara bo ṣe n gbe lẹyin Akintọla, nitori oun ti Akintọla ṣe fun Awolọwọ, Balewa ko gbọdọ ṣe bẹẹ fun un. Balewa paapaa ko fẹran Akintọla, awọn ohun to si n ṣe fun un nipa ọrọ Awolọwọ, o n ṣe e nitori aṣẹ ti ọga rẹ, Sardauna, pa fun un ni. Awọn ọmọ ẹgbẹ Hausa yii naa n fẹ ki wọn fi Awolọwọ silẹ, ki ọrọ naa ma si di ohun ti yoo da rogbodiyan ti apa ko ni i ka silẹ. Bo ba ṣe ti Tafawa Balewa olori ijọba nikan ni, yoo ti fi Awolọwọ silẹ tipẹ.

Nitori ki ẹnikẹni ma waa de lojiji ko ri oju-rere Ahmadu Bello, ko si di ohun ti wọn yoo tu Awolọwọ silẹ, ni Akintọla fi jade. Ki i ṣe pe o jade bẹẹ lasan, o jade pẹlu gbogbo agbara rẹ ni. Ori tẹlifiṣan lo lọ to fi n sọrọ rẹ, awọn tẹlifiṣan naa ko si ṣe ohun meji mọ ni gbogbo akoko to fi wa nibẹ, ọrọ rẹ ni wọn n sọ, lẹyin to kuro nibẹ naa tan paapaa, fun ọpọlọpọ wakati, ati titi ọjọ naa di ọjọ keji, ọrọ ti Akintọla sọ yii ni wọn n gbe sori afẹfẹ. Bẹẹ ni ki i ṣe tẹlifiṣan nikan, bi awọn onitẹlifiṣan ti n sọ ọ naa lawọn oniredio Western Region yii n sọ, awọn redio to ku naa si gba a, wọn n sọ eyi ti wọn ba le sọ ninu awọn ọrọ naa ni tiwọn, nitori ọrọ naa le ju. Akintọla ni oun waa ṣe alaye fun gbogbo ara West ohun to ṣẹlẹ laarin oun ati Awolọwọ ni, ati idi ti ija naa ko ṣe le pari laelae, ti oun ko si ni i ba a bẹbẹ pe ki wọn tu u silẹ lọgba ẹwọn laye oun.

Ọrọ idagbasoke Western Region lo ni oun waa sọ, ṣugbọn eyi to fi sọrọ Awolọwọ nibẹ ju idaji lọ, iyẹn lawọn eeyan ṣe sọ pe o kan fi ọrọ idagbasoke boju ni, ọrọ Awolọwọ gan-an lo waa sọ. Akintọla ni nnkan mẹta lo da ija awọn silẹ, nnkan mẹta ni, oun si fẹ ki gbogbo eeyan ba awọn gbọ ọ, ki wọn waa sọ boya oun jẹbi. O ni lakọọkọ, oun kọ ni, pe oun ko le ma kowo ijọba sinu apo ẹgbẹ Action Group, nitori oun mọ pe ohun ti ko dara ni. Bawo loun yoo ṣe maa ko owo awọn araalu sinu ẹgbẹ oṣelu awọn, ti wọn yoo si ni ki oun ma sọ ọ sita ki ẹnikẹni gbọ, bi oun si ko owo naa kalẹ, oun ko ni i mọ bo ṣe n lọ, boya ẹsẹ lo rin lọ tabi mọto lo wọ, oun Akintọla ko ni i mọ bi owo naa ti poora, wọn yoo si tun sọ pe ki oun mu owo mi-in wa sinu ẹgbẹ, oun si n mu un lọ. Igba ti oun waa yari pe oun ko le ko owo ijọba fun AG mọ, iyẹn nija fi bẹrẹ.

Lọna Keji, Akintọla ni ileeṣẹ NIPC ti wọn ni wọn da silẹ, awọn kan lo ni in, ileeṣẹ naa jẹ ijọba lowo to le ni miliọnu mẹfa owo pọn-un, bẹẹ lawọn ti wọn ni ileeṣẹ naa yoo tun maa halẹ mọ oun ti oun jẹ olori ijọba, ti wọn yoo ni awọn ko le san gbese, iye ti awọn ba si fẹẹ lo, afi ki ijọba ya awọn, igba ti awọn ba ri owo naa lawọn yoo too san an. Awọn mẹrin ti wọn si wa nidii ileeṣẹ naa ni Akinọla Maja, Sule Gbadamọsi, S.O Ṣonibare ati Alfred Rewane. O ni awọn mẹrẹẹrin yii, ko si ohun ti wọn ṣe ti ki i ṣe aṣegbe, nitori wọn ki i ba ẹnikẹni sọrọ ju Awolọwọ lọ, gbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ to ku ko jẹ nnkan kan loju wọn. O ni gbese ti wọn jẹ, iyẹn owo ti wọn ya lọwọ ijọba ti wọn ko san loun ni ki wọn san, ti oun si ni bi wọn ko ba san gbese naa, ijọba West yoo gba ileeṣẹ ọhun, iyẹn ni wọn tun n tori ẹ ba oun ja o.

O ni ẹṣẹ kẹta ti wọn ka soun lẹsẹ, ti wọn tori ẹ fẹẹ ba oun ja ni amọran ti oun mu wa pe ko si bi Western Region nikan ṣe le maa da ṣe, afi ki awọn maa ba awọn ipinlẹ to ku ṣe, ki awọn ma si sọ ara awọn di olodi ijọba apapọ, nitori ọwọ ijọba apapọ ni agbara ati okun ilọsiwaju orilẹ-ede wa. O ni amọran ti oun mu wa niyẹn o, pe ko si ohun to buru bi awọn ba n ba ẹgbẹ NPC, ẹgbẹ awọn Sardauna naa ṣe, ti awọn si jẹ ọrẹ ara awọn. O ni ṣugbọn Awolọwọ ko fẹẹ gbọ eleyii rara, nitori bi wọn ṣe n ri Awolọwọ yẹn, ohun ti wọn ko mọ nipa rẹ ni pe o ni igberaga gan-an ni. Igberaga naa si pọ debii pe o fi n koba Western Region, nitori igberaga rẹ lo ṣe loun ko ni i ba Gambari ṣe. O ni bẹẹ, awọn Gambari to n wi yii naa lo n ṣejọba, awọn ni Ọlọrun gbe ijọba Naijiria le lọwọ, ki lawọn waa fẹẹ ṣe ti awọn ko ni i ba Gambari ṣe.

Akintọla ni beeyan ba beere lọwọ awọn ọba ilẹ Yoruba, wọn yoo ṣalaye bi igberaga ati agidi Awolọwọ ti to, o ni gbogbo awọn ọba pata lo fi wọlẹ. O ni lọjọ kan, Awolọwọ sọ fun Akran, Ọba Badagry, pe oun yoo gba ade lori ẹ, oun yoo si sọ ọ di korofo lasan, bẹẹ naa lo si sọ fun awọn ọba ti wọn mura lati ba wọn pari ija pe bi oun ba ti pinnu kinni kan lọkan oun, koda bi baba oun ti ọrun sọ kalẹ, oun ko ni i yi kinni naa pada lae. Yatọ si iyẹn, Akintọla ni Awolọwọ ki i pe ẹnikẹni si nnkan rẹ, awọn o mọ ohun to n lọ ninu ẹgbẹ, funra ẹ lo n da nnkan ara rẹ ṣe. Prẹmia Western Region naa ni ki ẹnikẹni ma fi oju alaidaa wo oun o, nitori eeyan daadaa loun ni toun, Awolọwọ gan-an ni olori awọn alaidaa. O ni gbogbo rogbodiyan to n ṣẹlẹ ni West, Awolọwọ lo wa nidii ẹ, oun lo fa a, oun lo n lo Dauda Adegbenro lati ri oun ati ijọba fin.

“Bẹẹ, nigba ti awa wa ninu ẹgbẹ AG,” Akintọla lo n sọrọ yẹn o, “ipo wo ni Adegbenro wa? Ṣebi aisi nile ologinni ni ile ṣe di ile ekute, Adegbenro ko si ni ipo kẹwaa si iru awa, koda bi a ba n sọrọ awọn aṣaaju inu ẹgbẹ, a oo ti mu aṣaaju bii ogun ko too kan iru awọn Adegbenro yẹn, oun lo wa n ṣe bii olori AG loni-in! Ṣe ẹgbẹ niyẹn ni!”

Bayii ni Akintọla fibinu sọrọ lori redio ati tẹlifiṣan, ọrọ naa si da yanpọnyanrin silẹ kaakiri ilẹ Yoruba, ati ni Naijiria lapapọ.

(99)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.