Ẹgbẹ Dẹmọ lo ku tawọn ero n sare wọnu ẹ, atẹni to fẹ atẹni ti ko fẹ, kaluku lo fẹẹ gbọwọ Akintọla

Spread the love

Ko si ilu naa, tabi agbegbe kan, tabi adugbo kan, ti wọn ko ti pin si meji ni ilẹ Yoruba lọdun 1964. Ọpọlọpọ awọn mẹkunnu ilu, tonile talejo, ko kuro ninu Ẹgbẹ Ọlọpẹ, iyẹn Action Group, ẹgbẹ Ọbafẹmi Awolọwọ, wọn ni nibẹ lawọn yoo wa, ọpọlọpọ wọn lo si nigbagbọ pe bi Awolọwọ ti lọ naa ni yoo ṣe pada waa ba awọn, pe kinni kan ko ni i ṣe e, awọn mi-in si n sọ pe anjannu eeyan kan ni. Ṣugbọn pupọ ninu awọn olowo ati awọn alagbara ni ko le duro si ẹyin Awolọwọ, ọrọ naa le ju bẹẹ lasiko naa, ẹni to ba fẹẹ ṣe oṣelu to fẹẹ lowo, to si fẹẹ la nidii ẹ, tabi to fẹẹ ni agbara loootọ, afi to ba wa lẹyin ijọba to wa lode, ijọba naa si jẹ ijọba Ladoke Akintọla. Bi ẹni kan ba ti gba ti Akintọla ni daadaa gbogbo yoo maa tọ ọ lẹyin, yoo maa ri nnkan pọnla, bẹẹ ni yoo si lorukọ laarin awọn gbajumọ gbogbo. Ṣugbọn awọn araalu ki i fẹran iru wọn o, ija ni.

Ko ni i buru ko ma ku ẹni kan mọ ni, ẹni ti yoo ku ni a ki i mọ ni. Awọn araalu kan wa ti wọn ko le fi awọn aṣaaju tiwọn naa silẹ, inu ẹgbẹ ti wọn ba n lọ ni wọn yoo ba wọn lọ, ohun ti wọn ba si ni ki wọn ṣe naa ni wọn yoo ṣe. Loootọ awọn yii ko pọ, ṣugbọn awọn naa ni eeyan tiwọn, bi olowo tabi ọlọla kan ba si ti ni ẹgbẹ Akintọla loun n ṣe, gbogbo awọn ti wọn fẹ tirẹ ni wọn yoo tẹle e, wọn yoo si sọ awọn tiwọn ko tẹle e di ọta, wọn yoo si pin ilu tabi agbegbe naa si meji, ija naa yoo si maa lọ. Eyi lo ṣe jẹ ni gbogbo 1964 yii, ko si iṣọkan kan laarin awọn ọmọ Yoruba, ọta ti wọn n ba ara wọn ṣe ju eyi ti Hausa ti Ibo ṣe lasiko ogun Biafra lọ. Bẹẹ Yoruba kan naa ni wọn, ọrọ oṣelu lo sọ wọn dọta ara wọn, ọta naa si pọ debii pe awọn ti wọn n ba ara wọn ja yii ki i fẹ ki daadaa ṣẹlẹ si ọta wọn, wọn koriira wọn doju iku.

Ohun to ṣẹlẹ ni ilu Iwo niyẹn. Ṣe ole ko ni i ja agba ko ma ṣe e loju firi, ole lo si n mọ ẹsẹ ole i tọ lori apata. Awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC mọ pe Ọmọọba Lamuye to jẹ alagbara oloṣelu ni ilu naa ko ṣe tawọn taratara mọ, wọn mọ pe o ti n lọọ ba awọn eeyan Akintọla ṣepade loruloru, wọn mọ pe o fẹẹ sa lọ sinu ẹgbẹ naa ni. Ko ma di pe yoo di itiju si awọn lọrun ni wọn ṣe tete le e kuro, ti wọn ni awọn ko fẹ ẹ ninu NCNC mọ. Lamuye binu, o fẹsẹ halẹ, o ni oun ko lọ sinu ẹgbẹ kan, ara lo n fu awọn ọga oun ninu NCNC, iwa ti wọn n hu lo n ba wọn lẹru, oun ki i ṣe aṣẹwo oloṣelu ti yoo maa fo sinu ẹgbẹ kan bọ sinu omi-in. Amọ bi oun ti n sọ pe oun ki i ṣe aṣẹwo oloṣelu yii, bẹẹ lawọn eeyan rẹ niluu Iwo n laali awọn aṣaaju ẹgbẹ NCNC, ti wọn si ni ko yẹ ki wọn ṣe bẹẹ yẹn fun Lamuye, ati pe bo ba waa jẹ bẹẹ naa ni wọn ṣe fun un, ibi to ba n lọ lawọn n tẹle e lọ o, bo ba lo ya loni-in ki wọn lọ si Dẹmọ, o ti ya naa niyẹn.

Dẹmọ ni Lamuye fẹẹ lọ, ṣugbọn awọn eeyan rẹ ti wọn jẹ mẹkunnu ko fẹ, awọn olowo ati awọn ti wọn n jẹ ninu oṣelu to n ṣe lo fẹ ko maa lọ. Oun gẹgẹ bii oloṣelu naa mọ pe ni Western Region igba naa, ẹni to ba fẹẹ ri ohunkohun jẹ nidii oṣelu, afi ko ba Akintọla lọ. Igbagbọ ko tilẹ si fun awọn oloṣelu yii pe Awolọwọ yoo pada de mọ, nitori ko si ibi ti awọn eeyan bii Richard Akinjide de, tabi Adisa Akinloye, tabi Lekan Salami, ti wọn ko ni i sọ pe ẹgbẹ AG ti ku nilẹ Yoruba ati ni Naijiria, ko ni i gberi mọ, ati pe nigba ti ẹgbẹ AG ko ba gberi mọ, ko si bi Awolọwọ to ni ẹgbẹ yoo ṣe tun gberi ni Naijiria mọ, pe gbogbo ẹni to ba gbọn ko tete sa bọ silẹ ninu ọkọ Awolọwọ to fẹẹ ri sinu omi yii, ko tẹle Akintọla ninu ọkọ rẹ tuntun, ko ma di pe omi yoo gbe e lọ nigba ti ọkọ Awolọwọ yii ba doju de.

Olupolongo nla ni awọn mẹtẹẹta yii jẹ ni ilu Ibadan ati agbegbe rẹ, nigba ti wọn si jẹ ẹni to lẹnu niluu, pupọ ninu awọn eeyan ni wọn gba ohun ti wọn n sọ gbọ. Ṣe Awolọwọ kuku wa lẹwọn loootọ, awọn ti wọn si fi i sibẹ ko ṣetan lati mu un jade. Agaga nigba teeyan ba waa gbọ ọrọ Akintọla funra rẹ, bo si ṣe ti Fani-Kayọde ti i ṣe igbakeji rẹ ni, tọhun ko ni i ṣe iyemeji mọ, yoo gba pe ọna kan ṣoṣo lati ṣe oṣelu ni West naa ni lati ṣe ẹgbẹ Akintọla. Orukọ mẹta ni ẹgbẹ naa n jẹ, eyi ti ẹni to ba fẹẹ wọ ẹgbẹ naa ba si fẹran julọ ni yoo mu, ko ṣa ti pe ọkan ni. Ami ẹgbẹ naa ni ọwọ, bo ba ti ṣi oju ọwọ rẹ soke, to o si fi atẹlẹwọ rẹ han gbogbo aye, o ti gba ti ẹgbẹ Akintọla niyẹn, nitori ami ẹgbẹ naa ni “ọwọ”, itumọ rẹ si ni pe “Atẹlẹwọ ẹni ki i tan ni jẹ!” Iyẹn ni wọn ṣe maa n ṣi oju ọwọ soke lati fi atẹlẹwọ han gbogbo ẹni to ba jẹ ara wọn.

Bi eeyan ko si ṣe iyẹn bo ba ti ni Ẹgbẹ Dẹmọ loun wa, omi ẹkọ ẹkọ, naa ni, nitori Democratic to wa ninu orukọ ẹgbẹ naa ni wọn ṣe n pe e ni Dẹmọ. Awọn alakọwe ati awọn oloṣelu nla ni wọn n pe ẹgbẹ yii ni NNDP, nigba to si jẹ ẹgbẹ tuntun ni, gbogbo ọna ni Akintọla ati awọn eeyan rẹ n wa lati fi ko ero pupọ wọ inu ẹgbẹ wọn. Bi oloṣelu kan ba wa ni adugbo kan to lowo, ti wọn si mọ pe ọmọ ẹgbẹ mi-in ni, wọn yoo wa a ri. Bi wọn o ba gba iṣẹ aje to n ṣe lọwọ rẹ titi ti yoo fi mọ pe awọn ni awọn wa nidii rẹ ti yoo si rin mọ wọn, wọn yoo fi owo nla tan an debii pe ko ni i le yi ẹnu pada. Bi owo ko ba ran an, wọn yoo ṣeleri ipo agbara fun un. Wọn le ni awọn yoo fi iṣẹ akọwe ijọba, tabi pe ipo ti awọn yoo tun gbe e si yoo ju eyi to wa lọwọlọwọ bẹẹ yẹn lọ. Iru ohun ti wọn fi mu Lamuye naa ree.

Nigba ti yoo fi di ọjọ meji si mẹta ti wọn ni awọn yọ Lamuye ninu NCNC, awọn eeyan ẹ ti bẹrẹ si i bẹ ẹ pe ko ma duro mọ, ko maa ko awọn lọ sinu ẹgbẹ Akintọla, nitori Ẹgbẹ Ọlọwọ lawọn fẹ, Dẹmọ nile awọn. Nigba mi-in, oloṣelu to fẹẹ wọ inu ẹgbẹ tuntun yii naa ni yoo ṣeto tawọn eeyan rẹ yoo maa pariwo o, oun ni yoo sanwo awọn ti wọn n pariwo yii o, ti yoo ko awọn eeyan kan jọ ṣẹgbẹẹ kan, ti wọn yoo ya fọto, wọn yoo si kọwe ranṣẹ; wọn aa maa ni ohun ti awọn fẹ ki tọhun ṣe ree. Awọn oloṣelu Iwo yii jade, wọn ni awọn binu si NCNC, wọn ni to ba jẹ Lamuye n ṣe oju meji bii ida, awọn lawọn aa kọkọ mọ, tawọn yoo si mọ pe o fẹẹ lọ sinu ẹgbẹ mi-in, ti awọn yoo si fẹjọ rẹ sun awọn ọga awọn. Ṣugbọn Lamuye ko rin iru irin bẹẹ, wọn n purọ mọ ọn ni. Nitori bẹẹ, awọn ko tilẹ ṣe NCNC mọ, ki Lamuye maa ko awọn niṣo ni Dẹmọ.

O jọ pe yatọ si owo ati agbara to wa lọwọ ẹgbẹ NNDP yii, lilọ ti wọn lọ si ilu Ọyọ ati ohun to ṣẹlẹ si wọn nibẹ tubọ ti fun wọn ni agbara si i. Nigba ti Alaafin ati ọpọ awọn eeyan ti gba wọn lalejo l’Ọyọọ, ti ko si si ija, ti wọn si ti fohun ẹnu wọn da Awolọwọ lẹbi pe oun lo jẹ ki awọn maa ja nibẹ tẹlẹ, ọkan Akintọla ati awọn eeyan wọn balẹ, wọn ni awọn ti mu Ibadan, awọn ti mu Ọyọ mọ ọn, lati mu Ogbomọṣọ ko si ni i nira fawọn. Irinajo ti wọn ṣe si Ọyọ yii da bii tọniiki ni, niṣe lo fun wọn ni agbara si i, ko si yatọ si bii igba ti eeyan ba mu ọti oyinbo, ti ko mu un lamuju, ti ara rẹ waa n ya gaga. Bi wọn ti n ṣe yii lo tubọ n mu awọn eeyan sa wọ inu ẹgbẹ naa, wọn aa ni nigba ti Alaafin ati awọn ọba to ku ti sọ pe ko sewu, ta ni yoo waa maa tẹle Awolọwọ kiri nibi ti tọhun funra rẹ mọ pe ewu nla wa.

Ọwọ ẹrọ ni Akintọla ati awọn eeyan rẹ yoo fi sọ pe awọn fẹ ki ẹni kan maa bọ ninu ẹgbẹ awọn, igba ti tọhun ba ni oun ko wa, tabi to ba tu wọn jade ni ọrọ yoo di wahala, ti wọn yoo si sọ pe tọhun purọ mọ awọn ni, tabi o fẹẹ fi orukọ awọn gbokun, o kan fẹẹ ba awọn lorukọ rere ti awọn ni jẹ ni. Bi wọn ti ṣe fawọn aṣofin to ku ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ NCNC nile-igbimọ aṣofin niyẹn. Ẹgbẹ Akintọla ati ijọba rẹ halẹ mọ wọn pe eyi ti ko ba mọ bi oun yoo ti ṣe wọ inu Dẹmọ, afaimọ ko ma fọwọ gbe jombo laipẹ rara. Ṣugbọn ọkunrin kan wa ninu awọn olori NCNC Ibadan to lagbara, oun ni wọn n pe ni Adisa Adeoye, ipo ti Akinjide wa ninu ẹgbẹ NCNC tẹlẹ, ọkunrin naa lo kọkọ wa nibẹ, ija ipo naa si pẹlu ohun to jẹ ki Akinjide sa lọ sẹyin awọn Akintọla, to si ṣe bẹẹ di akọwe ẹgbẹ Dẹmọ.

Oun lo jade to ni ko si aṣofin kan ti yoo wọ inu ẹgbẹ Dẹmọ ninu awọn aṣofin NCNC mọ, koda ki ẹgbẹ naa forisọle, tabi ki awọn aṣaaju ẹgbẹ Dẹmọ yii maa yọ ina lẹnu. O ni bo ba ṣe pe NNDP da ara wọn loju, ti wọn si mọ pe atẹlẹwọ awọn ko ni i tan awọn jẹ, kin ni wọn n fi tipatipa fa awọn eeyan sinu ẹgbẹ wọn si. Ṣebi iwọfun ni itẹlọrun, ẹni to ba ki ni la a ki, bi eeyan ko ki ni, ka maa ba tara ẹni lọ ni. Ọrọ naa jo Akinjide ti i ṣe akọwe ẹgbẹ Dẹmọ lara, kia lo si ti bẹ jade, lo ba ni ki awọn eeyan ma da Adisa Adeoye lohun rara. O ni Adisa Adeoye ti wọn n wo yẹn ti kọkọ kọwe sawọn pe oun fẹẹ wọ inu ẹgbẹ Dẹmọ o, ṣugbọn awọn ohun to ni oun fẹẹ gba lawọn sọ fun un pe awọn ko ni, iyẹn lo ṣe pọ soke raja, to waa fẹẹ maa fẹnu ba awọn jẹ nigba ti awọn ko jẹ ko wọ inu ẹgbẹ awọn.

Akinjide ni aṣiri Adeoye ti tu si awọn lọwọ, awọn kuku ti mọ pe awọn Ibo to jẹ aṣaaju wọn ninu NCNC lati Enugu ati Eko n fọn owo ka, wọn n ko owo nla nla fun wọn lati fi fa oju awọn eeyan West mọra, o ni awọn fẹran iru owo to n wọ West yẹn ni tawọn, awọn yoo maa gba a a, awọn yoo si maa na an, awọn mẹkunnu ti wọn ba ti gbe owo lọọ ba yoo gba owo wọn daadaa, ṣugbọn ki wọn ti mọ pe ko si mẹkunnu ilẹ Yoruba ti yoo tun tẹle ẹgbẹ NCNC mọ, eyi ti awọn ṣe lẹyin wọn ti to gẹẹ. O ni gbogbo aye ti gba, Dẹmọ ni wọn ba lọ ni West, ẹgbẹ kan naa to ku ti wọn fẹẹ maa ṣe lẹgbẹ awọn. Akinjide ni bi Adisa Adeoye ko ba gbe jẹẹ, awọn yoo tu aṣiri ẹ to pọ ju bẹẹ lọ o, nitori awọn ni rẹkọọdu gbogbo ọrọ to sọ ati awọn ileri to le fawọn, to ni oun yoo gba gbogbo Ibadan fawọn bi awọn ba le ko owo kalẹ, pe ko ma jẹ ki awọn tu aṣiri oun sita o.

Ko si ohun to tun le dun-un-yan ju bẹẹ lọ ninu ọrọ oṣelu, iyẹn nigba ti eeyan ko ba ṣe kinni kan, ti awọn oloṣelu ba jade ti wọn si we kinni ọhun mọ ọn lọrun, to wọn ni ohun to ṣe niyẹn. Idi niyẹn ti Adeoye fi bẹ jade nijọ kan naa ti ọrọ Akinjide yii jade, o ni, ẹgbin gbun-un, ẹgbin oniyọrọ, o loun yoo waa lọ sinu ẹgbẹ Dẹmọ, Ọlọrun ko ni i jẹ ki oun ri i. Adisa Adeoye ni ọrọ to wa nilẹ yii ko le rara, gẹgẹ bi Akinjide ti wi, ko ma duro rara ki ilẹ ọjọ naa ṣu, nibikibi to ba ti ni ki oun waa pade oun loun yo wa, ki awọn oniroyin naa si tẹle awọn debẹ, ki awọn jọ waa wo adehun, tabi ọrọ ti oun ba ba ẹgbẹ Dẹmọ sọ.  O ni oun ko ba ẹgbẹ naa jokoo ri, nitori oun mọ pe okunkun ni wọn, bẹẹ ọmọ imọlẹ loun, ibi ti Akinjide ti waa ri eyi to n sọ yii, oun nikan lo mọ, o le jẹ oju-oorun lo ti ri i loju ala, tabi ko jẹ nigba to n ṣiranran ni.

Ṣugbọn ọrọ naa ko tan sibẹ, nitori bi oun ti n sọrọ lọwọ ni awọn ẹgbẹ NCNC ti jade, awọn olori ẹgbẹ naa ni gbogbo Western Region, wọn ni awọn naa nifẹẹ si ọrọ naa, awọn fẹ ki wọn fi orukọ awọn si i lati mọ ohun to n lọ. Wọn ni ko si ohun to le tẹ awọn lọrun bii ki Akinjide ko iwe ọwọ rẹ jade, pe to ba jẹ loootọ lo ni rẹkọọdu lọwọ, ko waa pilee rẹ fawọn, bo ba si jẹ o gba ohun Adeoye silẹ nibi kan ni, ko wa ki awọn feti ara wọn gbọ ọ. Wọn ni ohun ti awọn ṣe n sọ bẹẹ ni pe awọn mọ pe irọ ni Akinjide n pa, ko si iwe kankan lọwọ rẹ, bẹẹ ni ko ni ohun kan ti yoo fi gbe ọrọ rẹ lẹyin, o kan jokoo, o n purọ fun gbogbo aye ni. Awọn aṣaaju ẹgbẹ yii ni iru awọn irọ nla nla, irọ kabiti kabiti ti awọn Akinjide maa n pa fun Akintọla ree, ti oun naa yoo si ro  pe oun ri awọn eeyan daadaa yi oun ka, bẹẹ awọn eeyan buruku lo pọ lẹyin ẹ.

Gbogbo eeyan waa n wo o pe nibi ti ọrọ de yii, Akinjide yoo jade, yoo si ko awọn ẹri ọwọ rẹ to wi silẹ, aṣiri yoo si tu pe loootọ ni Adeoye waa ba oun. Ṣugbọn ọkunrin akọwe ẹgbẹ Dẹmọ yii ko jade, ko si ko kinni kankan wa, o kan n ba iṣẹ rẹ lọ ni. Nigba ti awọn eeyan si bẹrẹ si i yọ ọ lẹnu pe awọn iwe to ni o wa lọwọ oun nkọ, awọn ọrọ to ni Adeoye sọ, pe ṣe ko ni i ko wọn silẹ mọ ni, ohun to wi ni pe Adeoye funra ẹ mọ pe ootọ loun n sọ, ko niidi ki oun ṣẹṣẹ maa ko ẹri kan kalẹ mọ. O ni oun mọ Adeoye daadaa, ko le jokoo lai ri nnkan kan ṣe, bẹẹ ọwọ to wa yii, ti agbara ti bọ lọwọ NCNC to n ṣe, ko si iṣẹ gidi kan to wa lọwọ rẹ ti yoo ṣe, yoo kan maa jokoo kako soju kan ni, iyẹn lawọn ṣe fẹẹ ṣe e loore pe ko maa bọ ninu ẹgbẹ NNDP, ko waa gbadun ninu Ẹgbẹ Dẹmọ bawọn naa ṣe n gbadun, ṣugbọn nigba to si ti ni ko ri bẹẹ, ko maa jiya ẹ nibẹ.

Bi nnkan ṣe n lọ niyi, nigba ti yoo si fi di inu oṣu kẹfa, lọdun 1964, awọn ero to n lọ sitimọle ati ọgba ẹwọn ninu awọn oloṣelu ati mẹkunnu fẹrẹ ju iye awọn ti wọn wa nile lọ, nitori ojumọ kan, ẹwọn kan ni, ilẹ kan ko ni i mọ ki ọmọ Ẹgbẹ Ọlọpẹ, AG, tabi NCNC, kan ma ko si wahala ijọba Akintọla. Bi tọhun ba jẹ ẹni to gbọn, to si tete ri ẹni ba a bẹbẹ, pẹlu ẹjọ pe oun yoo wọ inu ẹgbẹ Dẹmọ, yoo bọ ninu rẹ. Ṣugbọn ti tọhun ba n ṣe agidi, to n sọ pe Awolọwọ ni baba oun, ẹyin rẹ loun yoo wa titi ti oun yoo fi ku, wọn yoo ju u si isalẹ ẹwọn lọhun-un wọn ko si ni i jẹ ko jade titi ti yoo fi ronupiwada, tabi ti wọn yoo gbagbe rẹ si ọgba ẹwọn pata. Ohun to n jẹ ki ero pọ ninu ẹgbẹ naa ree, atẹni to fẹ, atẹni ti ko fẹ, atẹni ti inu rẹ dun, atẹni ti inu rẹ ko dun. Amọ bi ero ti n pọ yii, bẹẹ naa ni Yoruba n pin si meji, ipinya naa si n gbooro si i.

Awọn ẹgbẹ Ọlọpẹ naa ko gbe ẹnu tiwọn naa fun alagbafọ, ohun ti iwe iroyin Tribune n ṣe fun Akintọla ko kere, imura kan ṣoṣo ti awọn naa mu ni ati ti ijọba rẹ ṣubu. Igba naa lo bẹrẹ si i lo iwe iroyin rẹ tuntun, Daily Sketch, bi wọn si ti dajọ si ibo bayii niwee naa turaka, o koju awọn ọta Akintọla, o loun ko ni i gba ki wọn fọga awọn wọlẹ tabi ki wọn gbajọba kuro lọwọ rẹ, ẹni to ba n ro iru rẹ ko le yatọ si ẹni to n wo iṣẹju akan, yoo kan pẹ leti omi lasan ni.

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.