Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ yari fun Fayoṣe l’Ekiti, won lafi ko sanwo awon

Spread the love

kede pe awọn ko nigbagbọ ninu ileri ti Gomina Ayọdele Fayoṣe tipinlẹ Ekiti ṣe tẹlẹ pe yoo san gbogbo owo to jẹ ko too lọ, eyi lo fa a ti wọn fi ni awọn ko ni i gba owo oṣu kọọkan to n san mọ, meji meji lawọn fẹ.

Eyi ni abajade ipade ti wọn ṣe lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta, nibi ti wọn ti sọ pe ko si bi gomina naa ṣe fẹẹ sanwo to jẹ tan to ba jẹ owo oṣu kọọkan lo fẹẹ maa san loṣooṣu

Gẹgẹ bi atẹjade ti Comrade Ade Adesanmi to jẹ alaga ẹgbẹ naa fọwọ si ṣe sọ, awọn oṣiṣẹ ti n sọ igbagbọ nu ninu ileri ti gomina ṣe, nitori o han pe ijọba ko fọkan si i. Wọn ni ko si bi gbogbo owo oṣu awọn oṣiṣẹ ati oṣiṣẹ-fẹyinti yoo ṣe di sisan pẹlu ọna ti ijọba n gba sanwo yii, afi ti wọn ba n sanwo oṣu meji nipari oṣu kọọkan.

Adesanmi ṣalaye siwaju pe o ti nira fawọn adari ẹgbẹ naa bayii lati fọkan awọn ọmọ ẹgbẹ balẹ pe gomina yoo mu ileri rẹ ṣẹ ki Ọmọwe Kayọde Fayẹmi too gbajọba loṣu kẹwaa, ọdun yii.

O rọ ijọba lati wa ojutuu sọrọ naa, nitori nnkan ko rọrun fawọn oṣiṣẹ mọ, paapaa fawọn ti kansu atawọn tiṣa ileewe alakọọbẹrẹ.

Bakan lo sọ pe kawọn eeyan ma ni i lọkan pe awọn oloṣelu kan lo n ti awọn lati kede ọrọ naa, igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ lawọn n ja fun, eyi to jẹ ojuṣe ẹgbẹ naa.

O waa sọ ọ di mimọ pe pẹlu bo ṣe ku bii oṣu meji pere ki ijọba yii pari, awọn ko le fọwọ sọya lori atilẹyin ati ifọwọsowọpọ awọn oṣiṣẹ pẹlu ijọba afi ti wọn ba gbe igbesẹ gidi lori wahala to wa nilẹ ọhun.

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.