Ẹgbẹ APC ti n lọ soko iparun -Oloye APC, Kawu Baraje

Spread the love

Ọkan gboogi ninu awọn oloye ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara, Alhaji Abubakar Kawu Baraje, ti ni bi eto idibo awọn oloye tuntun ẹgbẹ ṣe pin loriṣiiriṣii kaakiri orilẹ-ede Naijiria yii ki i ṣe apẹrẹ rere rara fun ẹgbẹ naa, eyi si le mu ki ẹgbẹ ọhun parun.

Baraje to ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ilọrin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, sọ pe lọwọlọwọ bayii, bii ipinlẹ mọkanlelogun leto idibo naa ti pin yẹlẹyẹlẹ. Lara awọn ipinlẹ ọhun ni awọn ipinlẹ to jẹ pe ẹgbẹ APC kọ lo n ṣakoso ẹ.

O ni ohun to ba oun lọkan jẹ pupọ ninu ọrọ yii ni pe awọn to wa lakooso ijọba gan-an lo n da ẹgbẹ APC ru, ” lara wọn lẹ ti maa ri minisita tabi awọn to dipo oṣelu kan mu. Awọn to wa ninu ẹgbẹ naa lo fẹẹ wo ẹgbẹ ọhun mọ ara wọn lori. Nnkan ko buru to eleyii nigba ta a wa ninu ẹgbẹ PDP.”

O sọ pe bi nnkan ba n lọ bo ṣe n lọ yii, iparun nla lo n duro de ẹgbẹ APC, ṣugbọn gbogbo ikilọ naa ni wọn kọti ikun si.

“A ṣekilọ lori iyansipo awọn oloye tuntun ṣaaju akoko yii, ṣugbọn wọn ko gbọ, nnkan ta a wo pe o le ṣẹlẹ lo wa n ṣẹlẹ bayii. Nnkan to buru jai ni ki ẹgbẹ ma sọkan. A ti pẹ ninu ẹgbẹ APC, a si ti ṣakiyesi pe nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa tun buru gan-an ju ohun to n ṣẹlẹ nigba ta a wa lẹgbẹ PDP lọ. Gbogbo ohun ta a ṣekilọ le lori lo tun n ṣẹlẹ bayii.

“Nigba ta a wa lẹgbẹ PDP, a tako aisi ibọwọ fun ofin, a tako bi wọn ṣe n gba awọn igun kan sẹgbẹẹ ati bẹẹ lọ. Gbogbo eleyii lo tun n ṣẹlẹ lẹgbẹ APC ta a wa.”

Nigba to n sọrọ lori bi Oloye Ọlagunsoye Oyinlọla ṣe fẹgbẹ APC silẹ, o ni eleyii ti n fi apẹẹrẹ lelẹ pe nnkan ko ri bo ṣe yẹ ko ri lẹgbẹ APC. O ni o fi han pe ohun to n ṣẹlẹ lẹgbẹ APC ko dun mọ Oyinlọla ninu.

“Awa ta a ku sinu ẹgbẹ naa ṣi nifẹẹ ẹgbẹ ọhun lo jẹ ka ṣi duro, gbogbo ọna la si fi n parọwa sawọn alatilẹyin wa lati ni suuru. Ṣugbọn ta a ba ba wọn sọ ọ ti wọn ko ba gbọ, a mọ igbesẹ to yẹ lati gbe.”

 

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.