Ẹgbẹ APC jawe olubori nibi atundi ibo ni Kwara

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu marun-un lo kopa ninu eto idibo lati yan ẹni to rọpo Funkẹ Adedoyin, aṣofin to jade laye ni Kwara, ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, ni wọn si ṣe e. Awọn ẹgbẹ naa ni, ẹgbẹ oṣelu APC, LP, PDP, PPN ati UPN.

Awọn oludije ẹgbẹ kọọkan ati ẹgbẹ ti wọn ṣoju fun ninu idibo naa ni: Raheem Olawuyi Ajulọopin (APC), Fẹmi Awokunle (LP), Jimoh Saheed Alatiṣe (PDP), Ajayi Layẹmi (PPN), ati Ọlaniyan Ayọbọde (UPN).

Oludije ẹgbẹ APC ati PDP ni wọn jọ jẹ ọmọ ilu Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹ̣pọdun, nipinlẹ Kwara.

Raheem Ọlawuyi Ajulọopin ti ẹgbẹ APC fi ajulọ han Jimoh Alatiṣe ti ẹgbẹ PDP pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹta o le diẹ (3,141).

Aṣoju ajọ INEC to ṣakoso idibo naa, Ọjọgbọn Abimbọla Adesọji, lo kede esi idibo yii ni nnkan bii aago mọkanla alẹ Satide.

Lapapọ APC ni ibo ẹgbẹrun lọna mọkanlelogun o le diẹ, (21,236), PDP ni ibo ẹgbẹrun mejidinlogun ati diẹ (18,095). Ẹgbẹ LP ni ibo aadoje (150), PPN ni ibo mẹrindinlọgọrin,(76), ti UPN si ni mejileogoji(42).

Ẹsi yii lo fidi ẹ mulẹ pe ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori.

Gomina Ahmed ti ẹgbẹ oṣelu PDP fa kalẹ gẹgẹ bii oludije wọn fun ipo sẹnẹtọ Guusu Kwara (South), yoo mura gidi lati le jawe olubori ninu idibo ọdun to n bọ.

Wọọrọwọ leto idibo naa waye kaakiri ijọba ibilẹ mẹrẹẹrin, iyẹn Oke-Ẹrọ/Ekiti/Isin/Irẹpọdun.

Lara awọn ibudo idibo ti a ṣabẹwo si ni Oke-Ipo, nibudo idibo keji niluu Ilọffa, Ọld Market 002, ileewe Jamaat Nasril, ibudo 001 ni Ilọffa, Aafin Ọlọọta tiluu Odo-Ọwa, ati  Ile Ala niluu Ayedun.

Ọlọọta tilu Odo-Ọwa, Ọba Joshua Adegbuyi Oluwatọba Adimula, sọ pe iṣoro to koju awọn oludibo lagbegbe naa ni ti ẹrọ to n yẹ kaadi idibo wo ti ko ṣiṣẹ daadaa. O ni o yẹ ki ajọ eleto idibo naa gbe ilana mi-in kalẹ fun iru awọn to ba ti ṣeto iforukọsilẹ, ṣugbọn ti wọn ko ti i gba kaadi idibo wọn lati le kopa ninu idibo naa. Ija bẹ silẹ niluu Ẹkan-Meje laarin awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu to n kopa ninu idibo naa. Awọn ṣọja atawọn ọlọpaa to wa nibudo idibo naa lo sare pana aawọ ohun.

 

Ọkan lara awọn alatilẹyin ẹgbẹ kan sọ pe awọn eeyan kan wa ti wọn n pe ara wọn ni ọtẹlẹmuyẹ, DSS, ti wọn si ni Abuja ni wọn ti ran awọn wa sibẹ.

Wọn ni ṣe ni wọn n gbe ẹnikẹni ti wọn ba ti ri to gbe foonu seti nitosi ibudo idibo.

Ọgbẹni Kọla Adeniji to jẹ ọkan lara awọn oludibo nibudo kẹsan-an, l’Odo-Ọwa, kin-in-ni, fẹdun ọkan rẹ han si bi wọn ko ṣe jẹ ki oun dibo nitori pe oun ko ni kaadi idibo alalopẹ.

Minisita feto iroyin ati aṣa lorilẹ-ede Naijiria,  Alhaji Lai Mohammed, to dibo ni Oro Ward II, Onikoyi, sọ pe inu oun dun si bi awọn eeyan ṣe jade lati dibo. O ni eto idibo lọ nirọwọ-rọsẹ.

Bakan naa ni ọkan lara awọn adari ẹgbẹ PDP, to tun jẹ kọmiṣanna, Demọla Banu, ni iṣoro kan to koju eto idibo naa ni ti ẹrọ to n yẹ kaadi idibo wo ti ko ṣiṣẹ daadaa lawọn ibudo kan. Ṣugbọn awọn araalu jade daadaa.

Ṣa, Ọga ajọ INEC nipinlẹ Kwara, Alhaji Attahiru Madami, gboriyin fun awọn oludibo bi wọn ṣe ṣeto naa wọọrọ lai fa wahala kankan.

Madami to sọrọ niluu Osi, nijọba ibilẹ Ekiti, lasiko ti eto idibo naa n lọ lọwọ sọ pe inu oun dun si bi alaafia ṣe wa, o si mu ori oun wu gidi. O ni ireti oun ni ki orilẹ-ede Naijiria wo awokọṣe ipinlẹ Kwara ninu idibo 2019 to n bọ.

O gba awọn oloṣelu to kopa niyanju lati gba esi idibo naa wọle lai fa wahala rara.

 

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.