Ẹgbẹ APC gba ile-ẹjọ lọ lori idajọ to kede Balogun-Fulani gẹgẹ bii alaga

Spread the love

Idunnu lo gba ọkan awọn ọmọ ẹgbẹ PDP niluu Ilọrin, bi ile-ẹjọ giga kan ṣe gbe idajọ kalẹ lỌjọruu, Wẹsidee, to kọja pe Ishọla Balogun-Fulani ni ojulowo alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara.

Iyalẹnu lo ṣi n jẹ fawọn eeyan pe bawo lọrọ APC ṣe waa kan ẹgbẹ PDP. Wọn ni eleyii fi han daju pe iromi Balogun-Fulani to n jo, oniluu rẹ wa nisalẹ odo.

Ṣe latigba ti igbimọ apapọ APC ti Adams Oshiomhole n dari ti fagile Balogun-Fulani pe ki i ṣe alaga ẹgbẹ mọ niyẹn ti gba ile-ẹjọ lọ. Ohun ti ẹgbẹ APC sọ nigba naa ni pe awọn ko ni igbẹkẹle ninu ọkunrin naa mọ, niwọn igba ti Bukọla Saraki to fa a kalẹ ti kuro. Wọn ni awọn ti le e kuro ninu ẹgbẹ.

Igbagbọ awọn eeyan ni pe o maa tẹle Saraki lọ si ẹgbẹ PDP, ṣugbọn si iyalẹnu wọn, ọkunrin naa ko lọ, niṣe lo taku pe oun ṣi ni alaga APC nipinlẹ Kwara. Bo ṣe n yan awọn oludije, bẹẹ lo n yan awọn oloye ẹgbẹ.

Igbesẹ to gbe ọhun lawọn to loye ni ki i ṣe lasan. Wọn ni o lohun to n ti i lẹyin to fi n ṣe bẹẹ. Awọn kan tiẹ ni o ṣee ṣe ko jẹ Saraki gan-an lo ni ko ṣi duro sinu ẹgbẹ naa lati maa da a ru, ki wọn si ma rojuutu ara wọn titi ti eto idibo 2019 yoo fi de.

ALAROYE ṣakiyesi pe pẹlu idunnu lawọn eeyan kan fi wọ aṣọ ẹgbẹjọda lọ si kootu ti idajọ ti waye lọjọ naa. Afi bii ẹni n lọ sibi ayẹyẹ lo ri.

Adajọ Taoheed Umar ti ile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Kwara to gbe idajọ kalẹ ni igbimọ alakooso ti Balogun-Fulani ko sodi ni ojulowo, nitori naa, ki awọn ti Bashiru Bọlarinwa lọọ jokoo ara wọn.

Umar ni igbesẹ tawọn alaṣẹ APC gbe lati tu igbimọ naa ka lodi sofin, ko si le fẹsẹ mulẹ rara. Bakan naa nile-ẹjọ tun ke si ajọ eleto idibo, INEC, lati gba orukọ awọn oloye ẹgbẹ ti ọkunrin naa yan.

Agbẹjọro olupẹjọ (Balogun-Fulani),  Abdulazeez Ibrahim, ni idajọ naa ti fidi rẹ mulẹ pe igbimọ alakooso APC ti Balogun-Fulani, n dari ni ojulowo.

Ṣugbọn agbẹjọro tawọn Bashiru Bọlarinwa, Kamaldeen Gambari, tako idajọ naa. O lawọn ti pẹjọ ko-tẹmi-lọrun.

Gambari ni idajọ naa ko le fẹsẹ mulẹ rara, nitori oun gbagbọ pe ile-ẹjọ ko-tẹmi-lọrun yoo fagi le e.

Ẹwẹ, igbimọ alakooso apapọ ẹgbẹ APC ti ni Balogun-Fulani pẹlu awọn to ko sodi ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn mọ, nitori o ti pẹ tawọn ti le wọn kuro ninu ẹgbẹ.

Alukoro apapọ APC, Mallam Lanre Issa-Onilu, ni awọn to n dunnu si idajọ ile-ẹjọ giga naa kan n ṣe e lasan ni. Idi ni pe igbimọ apapọ ni aṣẹ ati agbara lati le wọn kuro nigba tiwadii fi han pe wọn ṣeku-ṣẹyẹ ninu ẹgbẹ.

O ni o ṣe pataki lati jẹ kawọn eeyan mọ pe idibo abẹle waye nibi ti wọn ti yan awọn oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa lọdun 2019. Igbimọ tawọn adari ẹgbẹ gbe kalẹ lo ṣeto idibo abẹle naa ti ẹgbẹ si forukọ awọn to jawe olubori sọwọ si ajọ INEC.

 

 

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.