Ẹgbẹ APC ẹkun Ariwa Kwara tako iyansipo Lai ati Saraki bii minisita

Spread the love

 

Agbarijọ awọn ọdọ ẹgbẹ APC ẹkun Ariwa nipinlẹ Kwara ti tako iyansipo minisita feto iroyin ati aṣa ana, Alhaji Lai Mohammed ati Sẹnẹtọ Gbemisọla Saraki gẹgẹ bii minisita. Wọn ni ṣiṣe ojusaaju ati fifi ọwọ rọ ẹkun Ariwa Kwara sẹyin, ni ọrọ ọhun jọ.

Ninu atẹjade kan tawọn oloye ẹgbẹ naa: Zubair Aliyu Rogun (Patigi); Abubakar Mohammed Saddam (Kaiama); Wọle Ọlayiwọla (Moro); Umar Faruk Idris (Baruteen); Ibrahim Yahaya (Edu) buwọ lu, wọn ni iyalẹnu lo jẹ fẹkun naa nigba ti wọn gbọ ikede orukọ awọn minisita tuntun ti Aarẹ Muhammadu Buhari fẹẹ yan sipo naa.

Lai jẹ ọmọ ilu Oro, nijọba ibilẹ Irẹ̣pọdun, lẹkun Guusu Kwara. Ilu Ilọrin, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin, ẹkun Aarin-Gbungbun Kwara ni Gbemisọla Saraki ti wa ni tiẹ.

Ẹgbẹ ọhun gboriyin fun Aarẹ Buhari bo ṣe fun ipinlẹ Kwara nipo minisita meji, ṣugbọn wọn tako bi wọn ṣe pin kinni ọhun si ẹkun mejeeji naa.

Wọn ni loootọ ni Aarẹ lagbara labẹ ofin lati yan ẹni to ba wu u sipo, ṣugbọn o yẹ ki wọn pin in dọgba.

Gẹgẹ bi alaye ti wọn ṣe, lati ọdun 1999 si 2011 ni Aarin-Gbungbun Kwara ti ṣe gomina fun odidi ọdun mejila gbako, bakan naa ni ẹkun Guusu Kwara ti dipo gomina mu fun ọdun mẹjọ.

“Ẹkun Ariwa Kwara lo yẹ ko dipo gomina mu ninu idibo gbogbogboo to waye laipẹ yii lẹyin ogun ọdun ti wọn ko ti ri ipo naa, ṣugbọn lati gba alaafia laaye ati fun itẹsiwaju ipinlẹ Kwara, a fi tọwọ-tọwọ yọnda ohun to yẹ ko jẹ ẹtọ wa lati le jẹ ki ijọba to wa lori aleefa bayii jawe olubori.

“Iwadii fi han pe ẹkun ariwa fi ilọpo mẹta ju Aarin-Gbugbun ati Guusu Kwara lọ, a si kopa ribiribi lati gbe ijọba to wa nipo wọle. Aarin-Gbungbun lo maa n ko awọn ipo ijọba apapọ ju, Ẹkun-Guusu lo maa n tẹle e, ida mẹjọ pere ni wọn maa n fun Ariwa. Ta a ba wo gbogbo eleyii, ohun to daju ni pe Ẹkun Ariwa lo yẹ funpo minisita.”

Ẹgbẹ ọhun ni nitori irẹjẹ to n waye yii ni ko jẹ ki idagbasoke ba ẹkun Ariwa bii tawọn ẹkun meji yooku. Wọn ke si Aarẹ ati ijọba lati maa fi eyi sọkan ninu iyansipo yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe.

(42)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.