Ẹgbẹ APC ṣi ile ẹgbẹ tuntun, wọn ṣefilọlẹ ọkọ ipolongo

Spread the love

Alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara, Bashir Bọlarinwa, ti fi idaniloju han pe didun lọsan yoo so fẹgbẹ naa ninu idibo oṣu keji ati ikẹta ọdun yii.

Bọlarinwa sọrọ naa lasiko ti wọn ṣi ile ẹgbẹ tuntun ti ọkan lara awọn oludije funpo gomina, Yusuf Gobir, gbe kalẹ atawọn ọkọ ipolongo ibo, lagbegbe GRA, niluu Ilọrin, lọjọ Satide to kọja.

O ni o da oun loju pe ile ẹgbẹ naa lawọn yoo ti pejọ ṣajọyọ lẹyin tawọn ba jawe olubori tan. O fidunu han si Gobir atawọn ọmọ ẹgbẹ fun atilẹyin wọn lati ri i pe ẹgbẹ naa n tẹsiwaju.

Bọlarinwa ke si awọn ọmọ ẹgbẹ atawọn araalu lapapọ lati dibo wọn fun APC lọna ati ri ayipada rere nipinlẹ Kwara.

Minisita feto iroyin ati aṣa, Alhaji Lai Mohammed, awọn oludije APC, awọn oloye ẹgbẹ atawọn ọmọ ẹgbẹ lo pejọ lọpọ yanturu sibi eto naa.

Ninu ọrọ rẹ, Lai Mohammed gboriyin fun awọn oludupo mejila ti wọn jọ fa tikẹẹti gomina mọ ara wọn lọwọ bi wọn ṣe ṣatilẹyin fun ẹni to ja mọ lọwọ. O ni eleyii fi han pe iṣọkan wa ninu ẹgbẹ APC Kwara.

O ni idibo to n bọ yii, iṣẹ ti Ọlọrun ti pari fẹgbẹ APC ni, nitori pe o da oun loju pe gbogbo awọn oludije APC lo maa wọle, bẹrẹ lati ori Aarẹ Muhammadu Buhari.

Minisita ọhun ni: “Awọn ti yoo sa lọ kuro lorilẹ-ede Naijiria yii yoo pọ. Nitori ta a ba ti lu wọn, ko si ohun ti wọn yoo ṣe ju ki wọn gbe baagi wọn, ki wọn si sa lọ.

” Ẹ ma jẹ ki wọn dẹruba yin, Ọlọrun ti kuro lẹyin wọn, awọn araalu si ti pada lẹyin wọn. Gbogbo awọn tọọgi ti wọn n lo la maa palẹmọ ko too di ọjọ ibo. Ni Kwara lonii, ati ọmọde ati agba, ko si ẹni ti kọ mọ pe, ‘o to gẹ’.”

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.