Ẹgbẹ ADC ti fẹẹ tuka l’Oke-Ogun

Spread the love

Lọwọlọwọ bayii, wahala ti ṣẹlẹ laarin awọn agba ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), iyẹn Sẹnetọ Adewọlu Ladọja ati Oloye Micheal Adeniji Kọleoṣo, ẹni to wa ni ẹkun Oke-Ogun, pẹlu Oloye Ọlayiwọla Ọlakojọ, ẹni to wa ni ẹkun Ọyọ.
Nnkan ti a gbọ pe o fa a ni aigbọra-ẹni-ye to wa lori ẹni ti wọn yoo fun ni tikẹẹti ẹgbẹ lati dije funpo gomina lorukọ ẹgbẹ naa lọdun to n bọ. Ṣe awọn oludije mejila lo n fa tikẹẹti ẹgbẹ yii mọra wọn lọwọ, bẹẹ awọn kan si ti fẹsun kan Oloye Rashidi Ladọja pe oun lo fẹẹ sọ ara rẹ di apaṣẹ waa ninu ẹgbẹ naa, idi niyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ kan fi gbọna kootu lọ. Lagbegbe Oke-Ogun, nibi ti Oloye Adeniji Kọleoṣho ti jẹ adari wọn ni ọrọ naa ti fọ ẹgbẹ yii patapata. Ọkan ninu awọn alatilẹyin Kọleoṣo, Dapọ Popoọla, lo ko awọn alatilẹyin rẹ kuro ninu ẹgbẹ Labour lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, to si jẹ pe inu ẹgbẹ APC lo ko wọn lọ.
Ṣa, awọn eeyan ti n woye pe o ṣee ṣe ki ẹgbẹ oṣelu APC tun jawe olubori nibi eto idibo ọdun to n bọ nipinle Ọyọ, ti igun ti wọn n pe ni Unity Forum, ba fi le pada sinu ẹgbẹ naa.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.