EFCC gbe Fayoṣe lọ sile-ẹjọ, ni wọn ba tun da a pada si sẹẹli

Spread the love

Ọla, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni ile-ẹjọ giga to wa niluu Ikoyi, nipinlẹ Eko sun igbẹjọ lori gbigba beeli gomina ti ijọba rẹ ṣẹṣẹ kogba wọle l’Ekiti, Ọgbẹni Ayọdele Fayoṣe si. Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni ajọ to n ri si ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati iwa ajẹbanu, (EFCC), gbe gomina tẹlẹ yii wa si kootu lati bẹrẹ igbẹjọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an. Niṣe ni awọn agbofinro ati awọn oṣiṣẹ ajọ naa yi ọkunrin yii ka lẹyin to sọkalẹ ninu ọkọ bọọsi funfun ti wọn fi gbe e wa si ile-ẹjọ.
Ẹsun mọkanla ọtọọtọ ni ajọ yii ka si Fayoṣe ati ileeṣẹ rẹ, Sportless Investment Limited, lẹsẹ; ninu eyi ti aṣilo ipo ati inakunaa wa. Owo to din diẹ ni biliọnu mọkanlelọgbọn (30.9b), ni wọn fẹsun kan an pe o ṣe niṣekuṣe nigba to wa nipo. Ṣugbọn nigba ti wọn ka ẹsun naa si i leti nile-ẹjọ, Fayoṣe ni oun ko jẹbi.
Lasiko naa ni agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Kanu Agabi (SAN), to ti figba kan jẹ adajọ agba ni Naijiria ṣeto bi yoo ṣe gba beeli onibaara rẹ. Ṣugbọn agbẹjọro fun ajọ EFFCC, Ọgbẹni Rotimi Oyedepo, sọ pe loootọ loun ti ri iwe naa, ṣugbọn oun nilo asiko lati ṣe agbeyẹwo rẹ. Nidii eyi, Adajọ Mojisọla Ọlatoregun sọ pe oun ko le faaye beeli silẹ fun ọkunrin naa, afi ti eto gbogbo lori eleyii ba pari. O ni ki gomina tẹlẹ yii ṣi wa lọdọ ajọ EFCC titi di aarọ ọla ti igbẹjọ lori gbigba beeli rẹ yoo waye.
Ọpọlọpọ awọn alatilẹyin gomina yii to wa si kootu ni wọn ko jẹ ki wọn wọle. Ọkunrin naa paapaa ko ba ẹnikẹni sọrọ titi to fi wọnu motọ ileeṣẹ EFCC to gbe e wa. Ṣugbọn minista fun eto irinna tẹlẹ, Ọgbẹni Fani-Kayọde, sọ pe oun yoo duro ti Fayoṣe lasiko wahala yii lai yẹsẹ.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja ni Dokita Ayọdele Fayoṣe fẹsẹ ara rẹ rin lọ si ileeṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ yii gẹgẹ bo ṣe ṣeleri pe lọjọ ti oun ba pari ijọba oun loun yoo yọju si wọn nileeṣẹ wọn. Latigba naa lo ti wa lọdọ awọn ajọ yii.
ALAROYE gbọ pe ọpọlọpọ ibeere ti wọn n bi gomina tẹlẹ yii ni ko da wọn lohun, ohun to si n tẹnumọ ni pe ki wọn maa gbe oun niṣo nile-ẹjọ.
Ni gbogbo asiko to fi wa lọdọ wọn niluu Abuja, wọn ko jẹ ki ẹnikẹni ri i, bẹẹ ni ọkunrin ti wọn n pe ni Oshokomọlẹ yii ko ni anfaani lati ba ẹnikẹni sọrọ.
Lọsẹ to kọja yii kan naa ni ahesọ kan gbalẹ pe Alaga ajọ EFCC, Ọgbẹni Ibrahim Magu, sọ ninu fọnran kan pe bi Fayoṣe ba ku si akata awọn, ko sohun ti yoo ṣẹlẹ. Ṣugbọn ileeṣẹ yii ti ni ko si ootọ ninu ohun ti awọn kan n gbe kiri yii.
Ọla ni ireti wa pe ẹjọ rẹ yoo maa tẹsiwaju, ṣugbọn ko sẹni to ti i le sọ boya wọn maa fun un ni beeli ti igbẹjọ rẹ ba bẹrẹ lọla.

(23)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.