EFCC gbalejo ọga agba UNIOSUN ti wọn lo ṣe owo ileewe baṣubaṣu

Spread the love

Odidi wakati mẹwaa ni ọga agba ileewe Osun State University (UNIOSUN), Ọjọgbọn Labọ Popoọla, lo lakolo ajọ to n gbogun ti awọn ti wọn ba ṣe owo ilu baṣubaṣu, iyẹn EFCC, l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, nigba to n sọ ohun to mọ nipa iwe ẹsun tawọn oṣiṣẹ rẹ kọ sibẹ pe o na awọn owo ileewe naa ninakunaa.

 

Awọn oṣiṣẹ ti wọn ki i ṣe olukọ ninu ọgba naa, labẹ orukọ Joint Action Committee (JAC), ni wọn fi oniruuru ẹsun kan Popoọla pe o n na owo ileewe naa ni ina apa, bẹẹ lo si n ṣe eto iṣakoso ileewe naa lọna to wu u.

 

Lati ibẹrẹ ọdun yii ni alaga SSANU/JAC, Comrade Lekan Adiat, alaga NASU, Comrade Isaiah Fayẹmi, ati ti NAAT nileewe naa, Comrade Ismail Adeleke, ti sọ fun awọn oniroyin pe owo to le ni biliọnu mẹta Naira ni Popoọla ba ninu apo ileewe naa nigba ti wọn yan an gẹgẹ bii ọga agba ibẹ. Wọn ni iyalẹnu lo jẹ fawọn pe ṣe ni Popoọla ṣe owo naa bo ṣe wu u, ti ko si le ṣe isiro bo ṣe na an.

Bakan naa lawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ yii fi ẹsun kan Popoọla pe o na owo to le ni miliọnu lọna ọgọrun-un Naira to jẹ ti ileewe ọhun.

Eyi lo mu ki wọn kọwe si igbimọ alaṣẹ ileewe yii nigba naa, ṣugbọn ṣe ni wọn sọ pe Popoọla ko jẹbi pẹlu ọrọ to sọ fun wọn pe ṣe ni awọn eeyan yii n gbogun ti oun nitori oun ko gba wọn laaye lati maa huwa ibajẹ.

 

Idajọ igbimọ alaṣẹ ileewe naa labẹ idari Mallam Yusuf Ali, bi awọn oṣiṣẹ ti wọn wa lẹnu iyanṣẹlodi bayii ninu, paapaa pẹlu bi wọn ṣe da ọpọlọpọ awọn abẹnugan ẹgbẹ yii duro lai yẹ lọdun to kọja.

 

Idi niyi ti wọn fi kọ iwe si ajọ EFCC lati ba wọn da si ọrọ naa. Aago mẹsan-an aarọ ọjọ Wẹsidee la gbọ pe Popoọla de si ileeṣẹ ajọ naa niluu Abuja, nibi ti wọn ti fi ọrọ wa a lẹnu wo lori awọn iwe ẹsun naa.

 

Nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ni wọn too yọnda ọga ileewe yii lati lọ lẹyin to fi oniduuro meji silẹ.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.