Eeyan meji padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ni Ṣaki

Spread the love

Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ ni wọn ko ti i mọ orukọ ọkunrin ti oun pẹlu ọmọ ọdun meji aabọ kan jọ padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ ni nnkan bii aago meji aabọ ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii ni Budo Yellow, lagbegbe Arojẹ, bii kilomita mẹrin siluu Ṣaki, lati ilu Agọ-Arẹ, niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ. Ford Galaxy, elero meje kan ti nọmba rẹ jẹ Lagos GGE 622 ES, to n ko ero lati ilu Ṣaki lọ si Eko lo ṣadeede ṣubu lulẹ, ti eeyan meji si ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ọkan ninu awọn tori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa, Ayọbami Adio, to n ṣiṣẹ tiṣa nileewe alakọọbẹrẹ kan niluu naa sọ fun wa pe taya ẹyin ọkọ naa lo ṣadeede fọ lori ere, ti agbara awakọ naa ko si ka a mọ, nitori ere lo ti n ba a bọ tẹlẹ.
O ni ọkunrin to padanu ẹmi rẹ yii lo ṣadura lasiko ti ọkọ naa gbera ni gareeji to wa lagbegbe Poli Oke-Ogun.

O ni lẹyin ti wọn bẹrẹ irinajo ni taya ọkọ naa fọ lojiji, lẹsẹkẹsẹ ni ọkọ naa si wọnu igbo lọ, to si jẹ pe igi nla kan lo da a duro. 

Lasiko ti akọroyin wa de ibi iṣẹlẹ naa, a ri Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọtunba Moses Alake Adeyẹmọ, ẹni toun ati awọn ti wọn kọwọọrin pẹlu rẹ duro lati ran awọn to fara gba nibi iṣẹlẹ ijamba naa lọwọ.

Awakọ naa, Ọgbẹni Tajudeen Adebayọ, ṣalaye fun igbakeji gomina pe ko ti i ju iṣẹju mẹẹẹdogun toun gbera ni gareeji ti iṣẹlẹ naa fi ṣẹlẹ. Adeyẹmọ, da awakọ naa lẹbi, o ni ere asapajude lo fa ijamba to ṣẹlẹ ọhun.

O waa lo asiko naa lati kilọ fun awọn awakọ pe ki wọn rọra sare lasiko ti ọdun n pari lọ yii. O ni awọn awakọ ti sọ oṣu mẹrin to gbẹyin ọdun di oṣu ti wọn fi maa n dẹruba awọn eeyan, nitori ṣe ni wọn maa n sare asapajude lati pawo si apo ara wọn.

Ṣa, awọn oṣiṣẹ Ajọ ẹṣọ oju popo (FRSC), ẹka ti Oke-Ogun ati awọn oṣiṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri (Oyo State Emergency Agency), atawọn mi-in ti gbe oku awọn eeyan naa pẹlu awọn to farapa lọ si ileewosan aladaani kan.

 

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.