Eeyan meji ku, ọpọ tun farapa nibi ija awọn oloṣelu to waye niluu Ọwọ ati Ifọn

Spread the love

Wahala to n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun niluu Ondo,tun gbọna mi-in yọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ to kọja, pẹlu bi wọn tun ṣe gbẹmi ẹnikan ti wọn n pe inagijẹ rẹ ni Galala.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, oloogbe ọhun atawọn ẹgbẹ rẹ mi-in ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, ni wọn kọkọ doju ija kọ awọn alatako wọn lati inu ẹgbẹ Ave.

Awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ọhun ni wọn le lati agbegbe Ọka, nibi ti wọn ti bẹrẹ wahala naa wẹrẹwẹrẹ, titi ti wọn fi de Iyana Katoliiki, nitosi ileewe olukọni agba Adeyẹmi.

Nibẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ Ave ti raaye sa mọ wọn lọwọ, ti wọn si lọ ko ara wọn jọ lati doju ija kọ awọn Ẹiyẹ ti wọn jọ n fa a.

Wọn le awọn Ẹiyẹ titi de adugbo kan ti wọn n pe ni Ayọade, lagbegbe Ẹṣọ, nibi ti wọn ti raaye fibọn fọ Galala lori.

Eyi ni awọn ẹgbẹ rẹ ti wọn jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ Ẹiyẹ ri ti wọn fi sa wọ inu ile petẹẹsi kan lọ laduugbo naa, ti wọn si tilkun ile naamọri.

Inu ile ti wọn sa pamọ si ọhun lawọn ọlọpaa ti lọọ fi panpe ọba ko gbogbo wọn, bo tilẹ j pe awọn Ave to akọlu si wọn ti sa lọ kawọn ọlọpaa too de.

Ko din lawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje ti wọn padanu ẹmi wọn sinu ija to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ mejeeji yii ninu ou kejila, ọdun to kọja, si ou keji, ọdun yii.

Eyi to ya awọn eeyan lẹnu ju ninu iṣẹlẹ ọhun ni ti Lekan Akọmọlẹhin, oluọ ijọ Sẹlẹ kan to i wa nile-ẹkọ ijọ Sẹlẹ ti wọn ti n kẹkọọ nipa iṣẹ Oluwa, eyi to wa ni Imẹkọ, nipinlẹ Ogun Ni nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ kin-in-ni, ou kin-in-ni, ọdun yii, ni wọn pa ọmọ bibi ilu Ondo naa.

Ọjọ kọkanlelọgbọn, ti i ṣe aisun ọdun, ni wọn lo sare wale lati waa ba awọn eeyan rẹ ọdun.

Ile afẹsọna rẹ la gbọ pe o sun lalẹ ọjọ yii, bo ṣe di nnkan bii aago mẹrin idaji ni wọn lo kuro nibi to sun si lati maa bọ lọdọ awọn eeyan rẹ.

Asiko to de iyana adugbo kan ti wọn n pe ni Ifọrẹ, nitosi aafin ọba, lawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan pade rẹ, ti wọn si yinbọn pa a loju ẹsẹ.

Ọkan ninu awọn ẹbi wolii ọhun ta a forukọ bo laiiri sfun wa pe o da oun loju gbangba pe ẹni awọn to ku naa ko si ninu ẹgbẹ okunkun.

O ni o ṣe e ṣe ki wọn pa oloogbe ọhun nitori ọrọ obinrin lasan. Muari ileewosan ijọba to wa l’Ondo ni oku rẹ i wa lasiko to fi n ba wa sọrọ.

Ọpọlọpọ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun la gbọ pe awọn ọlọpaa ti fi panpẹ ọba gbe latari iẹlẹ ọhun, tọsantoru lo si ku ti wọn fi n paara awọn agbegbe ti wahala awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti n uyọ.

(71)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.