Eeyan meje ku lasiko ti awọn ọmọ ita n ja si owo ti wọn ji

Spread the love

O kere tan, eeyan meje ni wọn pade iku ojiji, ti awọn mi-in si farapa lasiko ti awọn ọmọ ita kan kọlu ara wọn lagbegbe Badia, niluu Eko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja. Atẹjade ti Chike Oti to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fi sita fidi iroyin yii mulẹ, o si ni awọn ti mu awọn afurasi marundinlogoji ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa. Lara awọn ti wọn ṣe kongẹ iku lasiko ija igboro yii ni Muyideen Saka, Wasiu Yusuf, Ejima ati Noah. Laarin awọn ọmọ igun ‘Suara Boys’ ati igun ‘Railway Boys’ ni ija naa ti ṣẹlẹ. Lasiko ti wọn kọlu ara wọn ni wọn ba dukia to le ni miliọnu meji Naira jẹ. Iwadii ọlọpaa fi han pe nigba ti awọn ọmọ igun Suara Boys ba n dari bọ lati ibi ti wọn ba ti lọọ ṣiṣẹ ibi wọn ni wọn maa n gba ọna Railway kọja. Awọn ọmọ ti Railway si maa n dena de wọn, ti wọn aa si gba awọn ohun ti wọn ba ji ko naa lọwọ wọn. Ṣugbọn lọjọ Sannde ọsẹ to lọ lọhun-un ni awọn ọmọ Suara Boys dihamọra, ti wọn si ya bo awọn ọmọ Railway Boys, ni wọn ba bẹrẹ si i yinbọn. Iṣẹlẹ naa lo mu ẹmi meji ninu awọn ọmọ ti Suara lọ. Eyi lo bi wọn ninu ti wọn fi pa meji ninu awọn ọmọ Railway. Orukọ awọn meji ti wọn pa gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ ni Ejima ati Noah. Ni awọn igun mejeeji ba tun bẹrẹ ija ni pẹrẹwu. Ibọn ilewọ oriṣiiriṣii ati ada ni awọn igun mejeeji ko dani. Lasiko rogbodiyan naa ni ọta ibọn ba Saka ati Yusuf, ti wọn si ṣe bẹẹ padanu ẹmi wọn lẹsẹkẹsẹ.

Oti ni ọmọ ẹgbẹ okunkun ni awọn igun mejeeji, lẹsẹkẹsẹ ti iroyin si tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ ni awọn ti ko awọn ikọ to n gbogun ti iwa ṣiṣe ẹgbẹ okunkun lọ si agbegbe naa.

O ṣalaye pe awọn ko awọn oku ti awọn ba nibẹ, ọwọ awọn si ti tẹ eeyan mẹta lori ẹsun naa.

O sọ pe ọdọ awọn ikọ to n ṣewadii iwa ọdaran to wa ni Panti, Yaba, ni awọn ko awọn afurasi tọwọ tẹ naa lọ fun iwadii to peye.

 

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.