Eeyan marundinlaaadọta jẹ anfaani ẹkọ-ọfẹ lasiko ayajọ ẹgbẹ awọn telọ

Spread the love

O kere tan, awọn to ku diẹ ka-a-to fun marundinlaaadọta lo jẹ anfaani ẹkọ-ọfẹ  ti ẹgbẹ awọn telọ, Nigerian Union of Tailors (NUT), ẹka tipinlẹ Kwara ṣe, gẹgẹ bii ọkan lara igbesẹ lati ro wọn lagbara.

Awọn to jẹ anfaani naa ni wọn mu kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ Kwara.

Alaga ẹgbẹ naa, Isiaka Abdulazeez-Ojoo, lo sọrọ ọhun nibi ayajọ ẹgbẹ awọn telọ alakọọkọ to waye niluu Ilọrin.

O ṣalaye pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ lawọn kan-an-nipa fun lati da igba Naira, owo yii lawọn si lo lati fi kọ awọn eeyan naa niṣẹ.

O ni eto ẹkọ-ọfẹ naa ati rira awọn ohun eelo ti wọn lo na ẹgbẹ ni miliọnu meji le ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un meje Naira, (2.7m)

Bakan naa lo ni yatọ si iṣẹ ti wọn kọ, ẹgbẹ tun ra awọn manṣiini iranṣọ atawọn ohun eelo mi-in fun wọn lasiko ti wọn gbayọnda lẹnu iṣẹ.

O ni igbesẹ naa jẹ ọna kan lati kun ijọba lọwọ lati fopin si iṣẹ ati oṣi, ati ipese iṣẹ fawọn ọdọ.

Alaga naa ni ẹgbẹ ọhun yoo gbiyanju lati tunbọ fi kun iye awọn to maa jẹ anfaani ẹkọ-ọfẹ naa lọdọọdun. O ke si ijọba atawọn ileeṣẹ nla nla lati ṣatilẹyin fun ẹgbẹ lọna ati mu ki eto naa tẹsiwaju.

AbdulAzeez-Ojoo gba awọn adari ẹgbẹ yii kaakiri ipinlẹ lorilẹ-ede Naijiria nimọran lati tẹle apẹẹrẹ eto ti ẹka ipinlẹ Kwara gbe kalẹ yii.

Awọn alaṣẹ ijọba atawọn aṣoju ileeṣẹ lo wa nikalẹ nibi eto naa.

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.