Eeyan marun-un farapa nibi ija ilẹ laarin Ọlọffa atawọn ara Ijẹhu

Spread the love

Eeyan bii marun-un lo farapa lọsẹ to kọja yii ninu ija ilẹ to bẹ silẹ laarin awọn araalu Ijẹhu, nijọba ibilẹ Ọffa, atawọn ọmọ Ọlọfa tilu Ọffa, Ọba Gbadamọsi Esuwọye.
Ọpọlọpọ araalu Ijẹhu lo pejọ lọsẹ to kọja lati fẹhonu han tako bi wọn ṣe ni Ọlọffa fipa gba ilẹ ti wọn fi n dako.
Awọn olufẹhonu han naa to gba gbogbo abawọle ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara kan pẹlu oriṣiriiṣi akọle ti wọn gbe lọwọ fẹdun ọkan wọn han lasiko ti ijokoo ile igbimọ n lọ lọwọ.
Alhaji Mọshood Adeogun to loun ni Baalẹ Ijẹhu to gbẹnusọ fawọn araalu naa sọ pe awọn janduku kan waa ka awọn eeyan mọ inu oko, wọn si bẹrẹ si i ṣa wọn ladaa.
Ọgbẹni Oyelọwọ Ismaila to gbẹnusọ fun abẹnugan ile-igbimọ aṣofin Kwara, Ali Ahmad, sọ fawọn olufẹhonu han naa lati lọọ kọ ẹdun ọkan wọn sinu iwe, ki wọn si fi sọwọ sile-igbimọ. O fi da wọn loju pe abẹnugan ile yoo gbọ ẹbẹ wọn.
Ninu esi Ọlọfa tilu Ọffa, Ọba Mufutau Eṣuwọye, lasiko ti akọroyin wa sabẹwo si i l’aafin rẹ, o ni lakọọkọ, Alhaji Adeogun ki i ṣe baalẹ, nitori ko sẹni to yan an.
O ni gege bii ọba ilu oun gbọdọ mọ si iyansipo rẹ, nitori naa, oun ko da a mọ gẹgẹ bii baalẹ.
O ni ilẹ kan ṣoṣo toun jogun lọwọ awọn baba nla oun ni ilẹ ti wọn n sọ yii. “Ori ilẹ naa ni Esuwọye akọkọ ti n da oko. Awọn Magaji mejeeji to fi silẹ ree lati maa mojuto ilẹ naa. Fun ọpọlọpọ ọdun ni wọn ti wa nibẹ.
“Ki n too gori oye lawọn mọlẹbi mi ti n sọ fun mi pe o yẹ ka ṣeto lati daabo bo ilẹ naa kawọn eeyan ma waa maa wọ ori ẹ lọna aitọ. Nigba ti mo si fẹẹ maa dako, mo gba ori ilẹ naa lọ. Ijẹhu jẹ ibi to tobi gan-an. Awọn agboole meje lo wa nibẹ, o si ti pẹ tawọn to n sọrọ yii ti n du ilẹ mọ awọn eeyan lọwọ.
“Kete ti mo dori oye ni mo pe gbogbo awọn agboole mejeeje ti ọrọ ilẹ naa kan, wọn si wọn ilẹ onikaluku, gbogbo wọn ni wọn gba aala ilẹ wọn ti ko si wahala kankan. Lẹyin ti wọn ṣe eleyii tan la too ṣakiyesi pe awọn eeyan to n ja si ilẹ yii ko ni ilẹ kankan nibẹ.”
Kabiyesi sọ pe nigba tawọn toun ran lọ sori ilẹ naa n ṣiṣẹ lọwọ lawọn ọdọmọkunrin bii mẹẹẹdogun kan waa ka wọn mọ ori ilẹ naa pẹlu ada ati ibọn mẹfa. Bi wọn ṣe debẹ ni wọn bẹrẹ si i yinbọn, ti wọn ṣa awọn to wa lori ilẹ naa ladaa.
“Awọn kan ti wọn fun nilẹ lati maa fi dako ni wọn waa fẹẹ sọ ọ di tiwọn. Ṣe bi wọn ba fun eeyan ni ilẹ lati maa lo o, njẹ o tunmọ si pe oun lo ni i? Awọn Mọgaji lo fi ilẹ Esuwoye han mi, ori ilẹ naa si ni mo lo. Bii eeka ilẹ ọgọta ni mo gbe katakata lọ lati fa kawọn araalu le ri ilẹ gbin agbado atawọn nnkan mi-in si. Miliọnu mẹẹẹdogun naira ni mo ti na lori ilẹ naa. Mo ti kede fawọn araalu to ba nifẹẹ lati da oko ki wọn lọọ maa dako lori ilẹ naa lọfẹẹ.”
O ni o ya oun lẹnu bawọn eeyan to n ja silẹ naa ṣe fẹẹ maa fa wahala, dipo ki wọn waa ba oun lati jọ sọrọ to ba jẹ pe wọn nilo ilẹ.

(59)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.