Eeyaan meta padanu emi won ninu molebi kan lẹyin amala ti wọn jẹ Stephen Ajagbe Ilorin

Spread the love

Iwadii ileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ilera nipinlẹ Kwara ṣi n lọ lọwọ lati mọ ohun to fa a teeyan mẹta ninu mọlẹbi kan ṣe padanu ẹmi wọn lọjọ kan ṣoṣo lẹyin ti wọn jẹ amala tan.

Awọn bii meje lo ṣi wa nileewosan, nibi ti wọn ti n gba itọju. Agboole Mọgaji Ọgọ, nile Oloogbin, lagbegbe Adewọle, niluu Ilọrin, niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Aburo olori ẹbi, Muritala Adisa, ṣalaye pe olori ẹbi naa, Hanafi Salaudeen, aburo olori ẹbi, Aishat Adisa pẹlu ọmọ ọdun mọkanla kan lo ba iṣẹlẹ naa lọ,wọn si ti sinku wọn nilana Musulumi.

Ṣugbọn ori ko ọmọ ọdun mejila kan yọ lẹyin igba to jẹ ounjẹ naa tan, nitori ṣe ni wọn sare fun un lagbo mu, lẹsẹkẹsẹ lo si pọ ounjẹ naa, ara rẹ si balẹ. Awọn ti wọn ko lọ si ọsibitu lẹyin ti wọn jẹun naa tan ni Sikiru Salaudeen, Kamarudeen Salaudeen, Khalid Salaudeen and Fasilat Salaudeen, Baridor Salaudeen atawọn meji mi-in.

Adisa sọ pe mọlẹbi naa ko ti i le sọ pato ohun to fa ajalu buruku naa. Ohun kan tawọn kan ri i ni pe lẹyin ti wọn jẹ amala tan lalẹ ọjọ tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni wọn bẹrẹ si ni i kigbe inu.

Awọn oṣiṣẹ eto ilera to lọ sile tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ bu diẹ lara elubọ ti wọn fi ro amala naa ati omi ti wọn n lo lati ṣe e, ki wọn baa le ṣayẹwo rẹ.

Ileewosan aladaani kan ni wọn kọkọ ko awọn eeyan ọhun lọ ko too di pe wọn ko wọn lọ si ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, fun itọju to peye.

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.