Ẹẹkan laarin oṣu mẹfa ni iyawo mi maa n fun mi ni ‘kinni’ ṣe-Atẹrẹ

Spread the love

Awọn Yoruba ti sọrọ tan, wọn ni ọwọ to ba n dun ni, a ki i fi bọnu aṣọ, ohun to ba si n dun ni ni i pọ lọla ẹni.

 

Owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu Ọgbẹni Paul Oluwatumininu Atẹrẹ to n bẹbẹ ni kootu kọkọ-kọkọ to wa niluu Ikarẹ Akoko, lati tu ibaṣepọ to wa laarin oun ati iyawo rẹ Abilekọ Modupẹ Atẹrẹ, ka lori bo ṣe kọ lati maa fun un ni ‘kinni’ ṣe ni gbogbo igba.

 

Baba ẹni ọdun marundinlaaadọta ọhun sọ ninu ẹjọ to ro ni kootu pe lati inu oṣu kẹta, ọdun 2017, ni olujẹjọ ti bẹrẹ iwa ko maa fi ibalopọ jẹ oun niya lai nidii.

 

O ni ọpọlọpọ igba lawọn ẹbi obinrin naa ti ba a sọrọ lori ọrọ yii,  ṣugbọn to kọ lati tẹti si wọn.

 

Atẹrẹ tun fẹsun ale yiyan kan iyawo rẹ, o loun ni ẹri aridaju pe o n fẹ ọkan ninu awọn olukọ to n kọ wọn niwee ni fasiti toun fowo ara oun ran an lọ.

 

Yatọ si ẹni to n fẹ nileewe, o loun tun mọ awọn ọkunrin mi-in ti obinrin naa n yan lale l’Akurẹ, nibi to n gbe.

 

Awọn ẹsun to tun ka si abilekọ naa lẹsẹ to fi mu ẹjọ wa si kootu ọhun ni ija ni gbogbo igba, sisa kuro nile ati biba awọn dukia rẹ jẹ.

 

O ni ki wọn tu awọn ka nitori pe ibaṣepọ to wa laarin awọn mejeeji ti su oun, bakan naa lo bẹbẹ pe ki wọn gba oun laaye koun maa tọju awọn ibeji ti awọn bi, nitori ilera awọn ọmọde naa.

 

Nigba to n fesi, Abilekọ Modupẹ sẹ kanlẹ lori ẹsun agbere ti ọkọ rẹ fi kan an, o ni iwa agbere to ti di baraku fun olupẹjọ lo ṣokunfa bi oun ṣe sa kuro nile rẹ.

 

Iya ọlọmọ meji ọhun ni oun ti figba kan ka ọkọ oun mọ ibi to ti n ṣagbere pẹlu awọn obinrin ti wọn jọ jẹ akẹkọọ nileewe toun wa.

 

Ọsọọsẹ lo ni ọkọ oun maa n lọ fun ayẹwo arun kogboogun (AIDS), nitori iṣekuse rẹ, eyi lo ni o ṣokunfa bi oun ṣe sa kuro nile rẹ, ko ma lọọ ko arun naa ran oun.

 

Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ boya oun naa fọwọ si ki wọn tu ibaṣepọ oun ati ọkọ rẹ ka, niṣe lobinrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ọhun kunlẹ, to ni rara.

 

O ni ohun ti oun n fẹ ni ki wọn ba oun bẹ ọkọ oun ko yi ero rẹ pada, nitori pe ko wu oun lati da tọju awọn ọmọ meji ti awọn bi.

 

Ibi ti wọn ba ẹjọ naa de ree ti Aarẹ kootu ọhun, Ajihinrere E.A. Adelabu, fi sun igbẹjọ siwaju.

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.