“Ẹbẹ kin ni Secondus n bẹ, kin lo n tọrọ aforiji fun” Fẹmi Fani-Kayode

Spread the love

Oloṣelu ẹgbẹ PDP, Fẹmi Fani-Kayọde, lo sọrọ yii pẹlu ibinu, o ni bi ẹni kan ba yẹ ko bẹbẹ lọwọlọwọ bayii, o ni awọn ẹgbẹ APC ni, fun gbogbo itajẹsilẹ, ikowojẹ ati ida-ọrọ-aje Naijiria ru. O tẹsiwaju nipa sisọ awọn aṣeyọri aarẹ tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, nile ijọba. O ni oun ba a ṣiṣẹ nigba to wa nile ijọba oun si mọ awọn aṣeyọri rẹ gbogbo.

Fani-Kayọde sọ pe ẹbẹ ti olori ẹgbẹ naa, Uche Secondus n bẹ yoo mu ki awọn alatako wọn sọ irọ dootọ mọ wọn lọwọ ni, o ni bi PDP ba nilati tọrọ aforijin fun ọdun Mẹrundinlogun to lo nile ijọba, afi ki awọn APC o lọọ gbe ibọn ki wọn si fi fọ ori ara wọn fun ijọba Naijiria ti wọn ṣe lọna ti wọn ṣe e yii.

O sọrọ buruku si awọn oṣelu APC o si pe ijọba Buhari ni ijọba opurọ ati onijibiti.

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.