Ẹ yee lo wa fun wahala oṣelu, awakọ ki i ṣe tọọgi—- Akọwe NURTW

Spread the love

Ọkan pataki ninu ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Ogun, Alaaji Abdulazeez Kayọde, to jẹ akọwe ẹgbẹ naa, ti kilọ fawọn oloṣelu pe ki wọn pada lẹyin awọn onimọto ti wọn maa n lo fun jagidijagan ninu oṣelu, o lawọn ki i ṣe tọọgi, ọmọluabi lawọn.

Nibi eto ikọwọ-bọwe alaafia (Signing of peace accord) tawọn ọlọpaa gbe kalẹ ni olu ileeṣẹ wọn ni Eleweeran, lọsẹ to kọja yii ni akọwe NURTW ti sọrọ yii.

Ọkunrin naa sọ pe asiko tawọn oloṣelu n lo awọn fun idaluru nitori ibo ti kọja. O ni awọn ti sun siwaju, ko si si aaye kẹnikan fi ọmọ tiẹ siluu oyinbo, ko maa waa ba aye ọmọ ọlọmọ jẹ nibi mọ.

Akọwe naa sọ pe, ‘A ti ni awọn to jade yunifasiti ninu wa daadaa, a ni awọn ti wọn ti gboye mastas. Emi ti mo n ba yin sọrọ yii, lẹksọra ni mi tẹlẹ nileewe gbogboniṣe ipinlẹ Kwara, ẹka iṣakoso awujọ ni mo wa ki n too darapọ mọ NURTW. Fun idi eyi, ẹgbẹ onimọto ti sun siwaju gan-an, eeyan pataki ni wa lawujọ, a dẹ n ṣiṣẹ wa, awa naa n pawo wọle sapo ijọba. Nitori naa, ẹyin oloṣelu, ẹ fi wa silẹ, ẹ jẹ ka ṣiṣẹ wa, ẹ ma lo wa fun wahala lasiko ibo, a ki i ṣe tọọgi rara’’.

Nitori ki wahala ma ba a ṣẹlẹ ninu ibo ọdun to n bọ yii naa lo mu ki kọmandi ọlọpaa to wa ni Eleeweran, labẹ CP Iliyasu Ahmed, gbe eto ikọwọ-bọwe alaafia yii kalẹ, nibi ti wọn pe awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu kọọkan si lati tọwọ bọwe pe awọn ko ni i fa wahala kankan.

CP Iliyasu Ahmed lo kọkọ kilọ fawọn oloselu pe ki wọn ṣọra fun sisọ ọrọkọrọ sira wọn lasiko ipolongo ibo, ki wọn dẹkun a n fa posta ẹgbẹ alatako ya, ki wọn si ma ṣe lo ẹnikẹni fun janduku ki wọn too le rọwọ mu.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu oloṣelu tọwọ ba tẹ pe o lọwọ si iwakuwa kankan bo ti wu ko kere to, iyẹn lawọn ṣe fẹ ki wọn kọwọ bọwe bayii, ẹni to ba si tapa si ohun to fọwọ ara ẹ kọ silẹ, ki tọhun yaa gbaradi fun iya ofin ni.

Nigba to n sọrọ lori awọn ẹgbẹ oṣelu to tọwọ bọwe adehun naa, alaga to n ri si gbigba awọn ẹgbẹ lamọran (Inter Parties Advisory Council) IPAC, Ọnarebu Abayọmi Arabambi, ṣeleri pe awọn yoo sa gbogbo ipa awọn lati ri i pe ibo 2019 yii ko nira nipinlẹ Ogun.

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.