Ẹ yee foku ọrun ṣe yẹyẹ, ko daa

Spread the love

Ọpọ awọn eeyan ti wọn gbọ iku Alex Badeh, olori awọn ọmọ ogun gbogbo ni Naijiria tẹlẹ, lọsẹ to kọja ni wọn n dunnu si iku ọkunrin naa, wọn ni Ọlọrun lo mu un. Ọga ologun agba ni Alex Badeh, oun si ni olori gbogbo awọn ologun pata nilẹ yii laye ijọba Jonathan. Ohun to jẹ ki inu awọn eeyan maa dun si iku oro ti ọkunrin naa ku ni pe lasiko rẹ ni wọn ko owo ti wọn ni ki wọn fi ra awọn ohun eelo ogun lati fi jagun awọn Boko Haram jẹ, wọn si darukọ oun naa pe o wa ninu awọn to kowo jẹ. Loootọ ile-ẹjọ ko ti i da a lẹbi, wọn ko si ti i fidi iye to ko jẹ mulẹ gan-an, ṣugbọn awọn araalu ti gba pe niwọn igba ti wọn ti le darukọ rẹ si ọrọ owo yii, ole paraku ni. O ṣee ṣe bẹẹ daadaa, oun ṣa lolori awọn ologun. Ṣugbọn ọrọ iku rẹ ko yẹ kawọn eeyan mu un bi wọn ti mu un yii, ohun ti wọn n ro ni pe Ọlọrun gbẹsan lara rẹ, wọn ko ronu pe ki i ṣe iru ọna bẹẹ ni Ọlọrun fi n gba ẹsan. Bi Ọlọrun yoo ba mu Badeh yii, ko ṣẹwọn ki wọn si gba gbogbo ohun to ji ko lọwọ rẹ, ko di ẹdun arinlẹ siluu yii ni iba daa julọ, iyẹn ni pe Ọlọrun mu un. Ṣugbọn iku oro ati awọn Fulani onimaalu to n paayan kiri ki i ṣe ohun ti ẹni kan yoo yọ si, nitori bi ọga ologun to fi gbogbo ọjọ aye rẹ ṣe iṣẹ ologun, to jẹ agbebọnrin funra rẹ pẹlu awọn ẹṣọ loriṣiiriṣii ba le ku tuẹ bẹẹ lọwọ awọn Fulani yii, ta lo waa ku ti ẹmi rẹ de nilẹ yii, ta lo ku ti awọn eeyan naa ko le yinbọn pa. Ogun to n ja wa yii ki i ṣe ogun to daa, ki i ṣe ogun ta a gbọdọ maa fi ẹni to ku ṣe yẹyẹ, ogun ti gbogbo wa gbọdọ mura silẹ de, ka mọ ọna ti a oo fi ṣẹgun awọn ti wọn n gbẹmi alaiṣẹ yii ni. Awọn ti wọn pa olori ologun, ta lo waa ku ti wọn ko le pa. Ohun ti ijọba paapaa fi gbọdọ mọ pe awọn ko mura rara si ọrọ awọn Fulani apaayan yii niyẹn, o yẹ kijọba Buhari ṣofin, o yẹ ki wọn lo awọn ṣọja si ọrọ yii, o yẹ ki wọn wa gbogbo ọna, ki wọn gba awọn ọmọ Naijiria lọwọ awọn afẹmiṣofo to n pa wọn kiri.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.