Ẹ woju ọmọọdọ to ji awọn ọmọ ọga rẹ ko sa lọ l’Ekoo

Spread the love

Idaji kutu ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa ri awọn ọmọ meji kan ti ọmọọdọ awọn obi wọn ti orukọ rẹ n jẹ Busayọ ji ko sa lọ lẹyin ọjọ keji to bẹrẹ iṣẹ nile wọn to wa ni Gbagada Phase 2, niluu Eko, wọn si ti da wọn pada fun awọn obi wọn. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, sọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni iroyin gba igboro Eko pe ọmọọdọ kan ji awọn ọmọ ọga rẹ meji ko lọ.

Lọjọ kẹrindinlọgbon, oṣu to kọja, ni Ọga Busayọ, Abilekọ Mutana, ran an pe ko lọọ ba oun ko awọn ọmọ wa ni ileewe, nitori iṣẹ oun ko faaye silẹ lati le lọọ ko wọn. Ṣugbọn ṣe ni Busayọ ti pari iṣẹ lori ọna lati ji awọn ọmọ yii, iyẹn ọkunrin, ọmọ ọdun mẹfa, ati obinrin, ọmọ ọdun mẹta ko. Pẹlu irọrun lo fi ko wọn nitori awọn alaṣẹ ileewe naa da a mọ pe ọdọ iya wọn lo ti wa.

Oti sọ pe iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fihan pe ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ikọ ajinigbe kan ni Busayọ, awọn ikọ naa lo si maa n ran an jade bii ọmọọdọ, ki wọn fi le maa ri ọmọ ji gbe. Ti Busayọ ba ti ri iṣẹ ọmọọdọ, niṣe lo maa n fa oju obi awọn ọmọ naa pẹlu awọn ọmọ yii mọra, to ba si ti ri i pe oun ti moju ilẹ tan lo maa ji awọn ọmọ naa ko sa lọ.

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti waa ṣekilọ fun awọn obi lati maa ṣọra fun awọn ti wọn ba maa gba bii ọmọ ọdọ, ki wọn si ṣewadii iru ẹni bẹẹ daadaa, ki wọn ma baa ko sọwọ.

Oti ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i gbagbọ pe Busayọ gan-an lorukọ ọmọ naa gẹgẹ bo ṣe sọ fun awọn ọga rẹ, ṣugbọn awọn fẹ ki awọn araalu da oju rẹ mọ daadaa, ki wọn si fi to ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa nitosi leti ti wọn ba ri i.

 

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.