Ẹ woju Kazeem, danfo loun atawọn ẹgbẹ rẹ fi maa n jale l’Ekoo

Spread the love

Ibrahim Kazeem, ẹni ọdun mejidinlogoji, lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ bayii, wọn ni oun pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ maa n fi ọkọ danfo jale, ti wọn yoo si tun ti ẹni to ba ko si pakute won lulẹ lati inu ọkọ lori ere.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, to fi iroyin naa to wa leti sọ pe Kazeem, ọmọ bibi Okeho, ni ijọba ibilẹ Kajọla, nipinlẹ Ọyọ ni olori ikọ ẹlẹni mẹrin naa.

Afurasi naa ṣalaye fawọn ọlọpaa pe oun pa iṣẹ awakọ bọọsi toun n ṣe ti fun iṣẹ ole jija nitori iyawo oun ni. O ni lẹyin toun fẹ iyawo ni wahala bẹrẹ si oun, nitori agbara oun ki i ka gbogbo nnkan ti iyawo oun maa n beere fun.

Kazeem sọ pe ṣe ni iyawo oun maa n sọ pe ki oun ṣe bi awọn ọkunrin gidi ṣe n ṣe, ki oun si wa kun iṣẹ ọwọ oun. Ọmọkunrin naa ni ẹgbẹrun mẹta Naira loun maa n ri nibi iṣẹ awakọ bọọsi toun n ṣe, ṣugbọn owo naa ko to oun i bọ ẹbi oun.

O ni nigba ti inilara iyawo oun pọ ni ọrẹ oun kan, Tijani, gba oun nimọran pe ki oun maa jale.  Kazeem ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe ṣe ni ẹni kan maa duro bii kọndọkitọ, ti Tijani yoo si maa gba owo ọkọ lọwọ awọn eeyan. O ni lojiji lo maa da wahala silẹ, ibi ti awọn ba si ti n pariwo ni awọn yoo ti gba dukia awọn eeyan, ki awọn too ti wọn lulẹ lori ere.

O ni ọna Surulere, niluu Eko, lọwọ ti tẹ oun, lẹyin ti ẹnikan ṣofofo ohun ti awọn n ṣe fawọn ọlọpaa.

 

(5)

1 Comment

  • Amazing blog! Do you have any recommendations for aspiring writers? I’m planning to start my own blog soon but I’m a little lost on everything. Would you recommend starting with a free platform like WordPress or go for a paid option? There are so many choices out there that I’m totally confused .. Any suggestions? Thanks a lot!

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.