Ẹ woju Ifeanyi, oniṣowo kan lo fẹẹ digunja lole tọwọ fi tẹ ẹ

Spread the love

Funra Ifeanyi Owoh lo huwa itufu, to fi n kiyesi ẹhinkule, nitori niṣe lawọn ọlọpaa kan da a duro laduugbo Billings way, Ọrẹgun, niluu Eko, wọn ni ko duro, awọn fẹẹ yẹ ẹ wo, ṣugbọn kaka ki ọmọ Ibo yii duro, niṣe lo fẹsẹ fẹ ẹ. Ihuwasi rẹ yii lo mu ifura lọwọ tawọn ọlọpaa naa fi gba ti i, ṣinkun ni wọn si mu un.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja ni iṣẹlẹ naa ṣẹle gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, ṣe fi ṣọwọ si wa. O ni Ifeanyi pẹlu ẹnikeji rẹ ni wọn n rin lọ ko too di pe wọn da wọn duro, ṣugbọn nigba ti wọn ko duro lawọn ọlọpaa naa fi ọkada le wọn, Ifeanyi nikan lọwọ wọn si tẹ.

Lasiko tọmọkunrin naa n ka boroboro fawọn ọlọpaa, o sọ pe ẹsiteeti kan loun pẹlu ekeji oun n lọ, nnkan tawọn si fẹẹ lọọ ṣe ni pe ọkunrin oniṣowo kan lawọn fẹẹ lọọ ja lole. Ọmọkunrin naa sọ fun awọn ọlọpaa pe awọn kan lo fun awọn lọwọ pe baba oniṣowo naa wa niluu, o fẹẹ waa ra ọkọ ayọkẹlẹ, owo ọwọ rẹ lawọn si fẹẹ lọọ gba ko too di pe aṣiri oun tu.

Nigba ti awọn ọlọpaa yẹ ara rẹ wo, wọn ba ibọn ilewọ kan, ọta ibọn mẹta pẹlu aake lọwọ rẹ.

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti gboṣuba kare fun awọn ọlọpaa to ṣiṣẹ naa, o ni wọn ko gbọdọ sinmi titi tọwọ wọn yoo fi tẹ ekeji Ifeanyi.

 

 

 

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.