Ẹ woju awọn mẹrin to n ṣe ayederu Ditọọ l’Ekoo

Spread the love

Francis Ume, ẹni ọdun mejilelọgbọn, Chidubem Achezie, ẹni ọdun mẹrinlelogoji,  Peter Ume, ẹni ọdun mẹrinlelogoji ati Ejike Jacob, ẹni ọdun mọkanlelogoji, lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ bayii pe wọn n ṣe ayederu ọṣẹ Ditọọ ati pafuumu Air Wick, laduugbo Okokomaiko, niluu Eko.

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ṣalaye pe Ọga ọlọpaa teṣan Okokomaiko, CSP Aliyu Lukman, niroyin tẹ lọwọ pe awọn afurasi yii n pese awọn nnkan ayederu.

O ni tirọọki ayederu ọṣẹ apakokoro ati pafuumu (air freshner), towo rẹ to miliọnu meje Naira lawọn ba nibẹ. Edgal waa pe akiyesi ileeṣẹ to n ṣe Ditọọ si i pe ki wọn tete mọ pe awọn kan ti n ṣe ayederu awọn ọja wọn. O ni ti ọpọ awọn iyalọmọ ba n lo o ti ko ba ṣiṣẹ, ṣe ni wọn aa maa bu ileeṣẹ to n ṣe e, lai mọ pe awọn kan lo ti n ṣe ayederu ọja wọn.

Agbofinro yii ni awọn ṣi n ṣewadii awọn afurasi yii ki awọn baa le mọ awọn mi-in ti wọn jọ n ṣiṣẹ naa.

ẹwọn de, Emmanuel Akinlabi, fun, wọn si ti da a pada si kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, niluu Eko, fun ẹsun idigunjale. Oun pẹlu awọn mẹta mi-in; Nurudeen Gbadamọsi, Emmanuel Akinlabi ati Samuel Elem, lo ja ọku

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.