Ẹ woju awọn afurasi to pa ọnarebu l’Ekiti *Iya atọmọ wa ninu wọn

Spread the love

O ṣee ṣe kawọn afurasi to ṣeku pa Ọnarebu Michael Adedeji to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin Ekiti lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ti balẹ si kootu lasiko tiroyin yii jade pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe sọ pe iwadii awọn ti fẹẹ pari.

 

Lọsẹ to kọja lawọn ọlọpaa ṣafihan Idowu Sunday (ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn), Adeniyi Wumi (ẹni ọdun mẹtalelogun), Lẹyẹ Ojo (ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn), Akindahunsi Damilọla (ẹni ọdun mejilelogun), Ọlaoṣebikan Babatunde (ẹni ọdun mejidinlaaadọta), Ọbamoyegun Dele (ẹni ọdun mẹtadinlogun) ati iya rẹ, Ọbamoyegun Bọla.

 

Alaye ti CP Asuquo Amba to jẹ kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti ṣe ni pe lọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, ọdun to kọja, lawọn eeyan naa kọlu mọlẹbi kan nibugbe awọn oṣiṣẹ fasiti Afẹ Babalọla, niluu Ado-Ekiti, nibi ti wọn ti gba mọto kan.

 

Lagbegbe Iworoko lọwọ ti tẹ Akindahunsi Damilọla pẹlu awọn ẹru to ji, oun lo si jẹwọ pe awọn lawọn lọọ ja otẹẹli Ọja lole, nibi ti wọn ti pa Ọmọwaye Kayode, ti wọn si ji mọto mẹta, iyẹn lọjọ kẹwaa, oṣu yii.

 

Nigba tiwadii tẹsiwaju lo han gbangba pe awọn naa lo pa Ọnarebu Adedeji lagbegbe GRA, niluu Ado-Ekiti. Iwadii fi han pe wọn ja aṣofin naa lole ni, ṣugbọn ko sẹni to mọ idi ti wọn fi pa a lẹyin ti wọn gba nnkan lọwọ ẹ.

 

Bakan naa ni Ọlaoṣebikan Babatunde ati Lẹyẹ Ojo lọọ fọ ile onile kan, nibi ti wọn ti ji kọmputa agbeletan, foonu, owo atawọn nnkan mi-in. Eyi atawọn idigunjale mi-in lawọn ọmọ ikọ yii ti gbe ṣe laarin oṣu diẹ si asiko yii.

 

Ọbamoyegun Bọla to jẹ iya Dele nikan ni obinrin to wa ninu awọn ti wọn mu, ọrọ rẹ si ṣe gbogbo awọn to n gbọ ọ ni kayeefi. Iya agbalagba naa ni agbẹbi loun nileewosan ijọba kan koun too fẹyinti, nnkan bii ọdun marundinlogoji loun si fi ṣiṣẹ.

 

Ariwo to ṣaa n pa ni pe oun ko mọ nipa awọn nnkan bii tẹlifiṣan, oogun abẹnugọngọ, ada, ẹrọ ayaworan, owo, batiri mọto atawọn nnkan ti wọn ba nile oun. O ni ọmọ oun ni Dele loootọ, ṣugbọn oun ko mọ pe o n jale.

 

Ṣugbọn iwadii ALAROYE, eyi ti obinrin naa pada jẹrii si fi han pe ọmọ rẹ meji lo wa lẹwọn lọwọlọwọ, ati pe Dele atawọn ti wọn ṣẹṣẹ jọ mu yii gan-an ti ṣẹwọn ri.

 

Ẹnikan to kọ lati darukọ rẹ fun wa sọ pe abẹ awọn pako kan ti wọn n ta lagbegbe ile ti Bọla atọmọ rẹ n gbe ni ikọ ọhun ko ibọn ti wọn n lo si, awọn ọlọpaa si ti waa ko awọn ibọn ọhun.

 

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, ẹnikan ta a forukọ bo laṣiiri tori ko yọ lọwọ ikọ yii sọ pe agbegbe Oke-Ọṣun, niluu Ikẹrẹ-Ekiti, lawọn eeyan ọhun waa ka oun mọ.

 

Ọkunrin to jẹ olori ẹsin naa ṣalaye pe, ‘’Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, ọdun to kọja, ni wọn wa sọdọ mi ni nnkan bii aago kan oru. Awọn meji lo wọle, ọkan ninu wọn ti mo da mọ daadaa wa lara awọn ti wọn mu yii.

 

‘’Ọlọrun lo mọ bi wọn ṣe ja ilẹkun wọle nitori gbii nikan ni mo gbọ ti mo fi taji, ki n too mọ nnkan to n ṣelẹ, wọn ti de palọ mi. Wọn gba owo to le ni ẹgbẹrun mẹwaa, bẹẹ ni wọn gba ọkọ Toyota Corolla mi.

 

‘’ Wọn tun gba kọmputa agbeletan mi mẹta pẹlu foonu iyawo mi, iyẹn foonu Tecno ati Huawei. Ada ati ibọn oloju-meji kan ni wọn gbe dani.

 

‘’Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe wọn ko ṣe mi nibi.’’

 

CP Amba ti waa ṣeleri pe kootu ni yoo yanju ọrọ awọn eeyan ọhun, bẹẹ lo ke sawọn araalu lati maa ran ọlọpaa lọwọ kawọn oniṣẹ ibi ma baa ribi sapamọ si.

 

(64)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.