Ẹ wo Taju atọrẹ rẹ, foonu ni wọn maa n ji l’Oṣodi

Spread the love

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni awọn ọlọpaa ayaraṣaṣa (RRS), ti ipinlẹ Eko mu awọn afurasi ole meji, Tajudeen Adedayọ ati Courage Agu, wọn ni wọn wa lara awọn ole to maa n yọ foonu lapo awọn eeyan l’Oṣodi.
Taju, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ati Courage, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ni wọn ka mọ ibi ti wọn ti n dunaa-dura pẹlu awọn ti wọn fẹẹ ta foonu naa fun.
Nigba ti Taju ri i pe aṣiri oun ti fẹẹ tu, niṣe ni wọn lo fọgbọn fun ọkan ninu wọn ni foonu to ji yii, ṣugbọn nibi ti wọn ti n le ọmọkunrin naa lọ lo ti sọ foonu naa silẹ, to si sa lọ, ṣugbọn ọwọ pada tẹ Taju ati Courage. Awọn mejeeji ni wọn jẹwọ pe foonu ni awọn maa n ja gba l’Oṣodi.
Ninu alaye ti Taju ṣe fun wọn, o sọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ati irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ni awọn maa n ri foonu ja gba ju, nitori awọn eeyan maa n kanju ni awọn ọjọ mejeeji yii.
Ṣa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, ti sọ pe awọn yoo ko awọn afurasi naa lọ si kootu lẹyin ti awọn ba pari iwadii awọn lori ẹsun ti wọn mu wọn fun naa.
Bakan naa, ọwọ awọn ọlọpaa ayaraṣaṣa tun tẹ ọmọkunrin kan to maa n ra foonu lọwọ awọn ole. Gẹgẹ bi alaye ti wọn ṣe, wọn ni afurasi naa ti wọn forukọ bo laṣiiri ra foonu yii lọwọ awọn ti wọn ja a gba lai mọ. Wọn sọ pe awọn to ja foonu naa gba ti fi gba owo jade lasunwọn ẹni to ni i ko too di pe wọn ta a. Ẹni ti wọn ta a fun yii ni awọn ọlọpaa ni wọn ṣẹṣẹ tu silẹ lẹwọn, ṣugbọn wọn lo ti jẹwọ pe oun ko si lara awọn to ja ẹni to ni foonu naa lole rara, oun kan ra a lọwọ wọn ni.
Wọn waa ṣekilọ fun awọn araalu lati dẹkun rira awọn ọja aloku lọwọ awọn ti wọn ko da mọ, pẹlu afikun pe awọn ti taari ọmọkunrin naa lọ si ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran ni Panti, fun iwadii to lọọrin.

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.