Ẹ wo Shock-up, wọn ni wọn lu u loogun nibi to ti n ja tikẹẹti lori ẹ fi yi Ṣugbọn awọn kan ni kokeeni lo ba aye ẹ jẹ

Spread the love

Shock-up ni wọn n pe e nigboro Abẹokuta, oun paapaa ko mọ orukọ abisọ ẹ mọ. Bi a ṣe beere lọwọ ẹ to, ohun to n sọ ni pe Shock-up lorukọ oun. Ṣugbọn beeyan ba ti ri irisi ọkunrin giga naa, yoo ti mọ pe ko gbadun, o ti ni arun ọpọlọ.

Ohun to kọkọ pe akiyesi wa si i ni Kutọ ti a ti ri i lọjọ Ẹti to koja yii ni bo ṣe n ṣubu lulẹ kiri, ti ipakọ ẹ ti bo, to si n ṣẹjẹ. Iwaju ṣọọṣi kan lo kọkọ jokoo si, ero pe pitimu lori ẹ ti wọn n wo o. Igba ti akọroyin wa yoo fi sun mọ ọkunrin yii, o ti dide, o si ti ta gọọgọ de ọwọ isalẹ Kutọ.

Ohun ti awọn eeyan to n woran ẹ sọ fun wa ni pe tikẹẹti ni Shock-up maa n ja ni gareeji Kutọ, wọn ni awọn ọlọkada lo n ja tikẹẹti fun. Awọn kan sọ fun wa pe aṣeju awọn ti wọn maa n ja tikeẹti naa maa n pọ ju, wọn ni ọmọkunrin yii naa maa n kọja aaye ẹ pupọ bi ogogoro ṣe ti ba aye rẹ jẹ to.

Wọ ni o ṣi ja tikẹẹti l’Ọjọbọ ti i ṣe ọjọ kẹtala, oṣu yii, ọjọ naa lo si fara kaaṣa, ti ẹnikan lu u loogun ninu awọn to n ja tikẹẹti fun, nigba to fẹẹ fagidi gbowo lọwọ iyẹn.

N la ba fi sun mọ Shock-up lati gbọ ọrọ kan tabi meji lẹnu ẹ, nigba naa lo si sọ fun ALAROYE pe Shock-up lorukọ oun. O ni ọmọ Itoko, l’Abẹokuta, loun. O loun ṣi ni baba, ṣugbọn iya oun ti ku.

O fi kun un pe oun ni iyawo tẹlẹ, koda, obinrin naa bimọ mẹta foun, ṣugbọn o ti da ọmọ silẹ bayii, o ti sa lọ. Ki lo de tiyawo fi sa lọ la bi i, o loun ko le sọ, ṣugbọn oun kọṣẹ kafinta ṣa, iyẹn loun n ṣe tẹlẹ koun too bẹrẹ si i ja tikẹẹti ni Kutọ.

Akọroyin wa beere pe ki lo de to n ṣubu kiri, ti ẹjẹ wa nipakọ ẹ, pẹlu apa lara ẹ kaakiri. Ọkunrin to to ẹni aadọta ọdun loun naa sọ pe oun ṣaa n ṣubu naa ni, oun naa ko mọ nnkan to de. O ni awọn olọkada si kọ, wọn ko fẹẹ gbe oun dele. Oun si fẹẹ de ile awọn n’Itoko, ṣugbọn wọn ko gbe oun, oun yoo yaa maa fẹsẹ oun rin lọ ni. (Kutọ s’Itoko ki i ṣe irin kekere o).

A beere orukọ ọga ẹ nibi to ti n ja tikẹẹti, o ni Gẹdu ni. Iwadii la fi mọ pe Akeem Gẹdu ni ọga ẹ to n sọ naa n jẹ, n la ba fi wa ọkunrin naa lọ si beesi ẹ to wa lagbegbe Park Inn.

Alaye ti ọga naa ṣe fun wa ni pe Shock-up ti n ṣiwere tipẹ, o ni ṣugbọn oun ko gbagbọ pe ẹnikan lo lu u loogun. O lo pẹ to ti n mu oogun oloro ti wọn n pe ni kokeeni, igbo ati oriṣiiriṣi ijẹkujẹ, bẹẹ lo si maa n fa kinni kan sara lati inu sirinnji ti wọn fi n gun abẹrẹ oyinbo.

Oogun oloro buruku kan ti wọn n pe ni Sayẹnsi (Science) ni Gẹdu sọ pe Shock-up maa n lọọ gba sara bii abẹrẹ. O ni to ba fa kinni naa yo tan ni were rẹ yoo tun gba okun si i, nigba naa ni yoo maa la ori rẹ mọlẹ, ti yoo maa ṣe ara ẹ nisekuṣe.

Alagba yii fi kun un pe oun ti mọ Shock-up pẹlu iwakiwa tipẹ, o ni ole han-un ni tẹlẹ, kaye ẹ ma baa bajẹ tan lawọn ṣe n gbe tikẹẹti le e lọwọ pe koun naa maa ja a fawọn ọlọkada. O ni sugbọn laarin oṣu kan, Shock-up le ma ja to ogun tikẹẹti, nigba ti ko mu iṣẹ naa ni koko, to jẹ ko ṣaa maa gba lọwọ meeri kiri ti mọ ọn lara.

Ọga rẹ yii tẹsiwaju pe oun mọ iyawo Shock-up, o ni nigba ti ọkunrin yii fẹẹ lu u pa niyẹn da awọn ọmọ silẹ fun un to sa lọ. ’’Emi ti mo maa n da Shock-up dubulẹ ree, ti ma a bo igi si i nidii to ba ti luyawo ẹ, tiyẹn dẹ waa fẹjọ ẹ sun mi.

‘’Igba ti a pari ẹ titi to su wa, ti obinrin yẹn naa ko dẹ le fara da a mọ lo sa lọ ni tiẹ. Bo ṣe n ṣaye ẹ kaakiri niyẹn o, emi o ro pe ẹnikẹni fi oogun na an lo fi n ṣe werewere to n ṣe kiri yẹn’’

Bẹẹ ni ọkunrin to ni ka ma ya fọto oun naa ṣalaye nipa Shock-up, baale ile ti imukumu sọ di were ojiji.

A ba awọn ọlokada mi-in naa sọrọ ni gareeji to ti n ja tikẹẹti, wọn ni imukumu pọ fun Shock-up. Ṣebi a ri i bi gbogbo eyin ẹnu ẹ ṣe yọ tan, ti eyi to ku nibẹ ti jẹra mọ ọn lẹnu nibẹ, wọn ni iṣẹ buruku ti ogogoro ati oogun oloro to n mu n ṣe laye ẹ niyẹn.

Lori idi ti wọn ko ṣe fẹe gbe e lọ sile ẹ n’Itoko, awọn ọlokada yii sọ pe o ti muti yo, ko si imi gidi kan ninu ẹ mọ, niṣe lo n ṣubu yẹgẹ. Wọn ni bawọn ba gbe e sori ọkada, to ba lọọ jabọ, ọran niyẹn lọdọ ijọba. Iyẹn ni kaluku ṣe n sa fun un, ti wọn ko gbe e.

Were ko kuku mo pe ohun to n ṣe oun ko daa, bi were ba mọ pe ohun to n ṣe oun ko daa ni, ko ni i wọja nihooho. Shock-up ko mọ pe nnkan n ṣe oun. Niṣe lo ni oun ko mọ ohun toun ṣe fawọn ọlọkada ti wọn fi n fiya jẹ oun bayii,  bẹẹ, wan taosan wa lọwọ oun, waso meji (Waso meji lo n pe ni egbẹrun kan Naira).

Titi ta a fi kuro lọdọ ẹ lọjọ naa, Shock-up n ṣubu kiri ni o, bẹẹ lo n fẹsẹ rin lọ sile rẹ to ni o wa ni Itoko, lẹgbẹẹ gbọngan iṣẹmbaye kan.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.